A mọ èyí pé a kò ṣe òfin fún àwọn eniyan rere, bí kò ṣe fún àwọn oníwàkiwà ati àwọn alágídí, àwọn aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn oníbàjẹ́ ati àwọn aláìbìkítà fún ohun mímọ́, àwọn tí wọn máa ń lu baba ati ìyá wọn, àwọn àgbèrè, àwọn ọkunrin tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀, àwọn gbọ́mọgbọ́mọ, àwọn onírọ́, àwọn tí ó ń búra èké, ati àwọn tí ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó dára