1
TIMOTI KINNI 3:16
Yoruba Bible
Kò sí ẹni tí kò mọ̀ pé àṣírí ẹ̀sìn wa jinlẹ̀ pupọ: Ẹni tí ó farahàn ninu ẹran-ara, tí a dá láre ninu ẹ̀mí, tí àwọn angẹli fi ojú rí, tí à ń waasu rẹ̀ láàrin àwọn alaigbagbọ, tí a gbàgbọ́ ninu ayé, tí a gbé lọ sinu ògo.
Compare
Explore TIMOTI KINNI 3:16
2
TIMOTI KINNI 3:2
Nítorí náà, olùdarí níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn; kò gbọdọ̀ ní ju iyawo kan lọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ọlọ́gbọ́n eniyan, ọmọlúwàbí, ẹni tí ó fẹ́ràn láti máa ṣe eniyan lálejò, tí ó sì fẹ́ràn iṣẹ́ olùkọ́ni.
Explore TIMOTI KINNI 3:2
3
TIMOTI KINNI 3:4
Ó gbọdọ̀ káwọ́ ilé rẹ̀ dáradára, kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.
Explore TIMOTI KINNI 3:4
4
TIMOTI KINNI 3:12-13
Diakoni kò gbọdọ̀ ní ju aya kan lọ; ó sì gbọdọ̀ káwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáradára ati gbogbo ìdílé rẹ̀. Nítorí àwọn tí wọn bá ṣe iṣẹ́ diakoni dáradára ti ṣí ọ̀nà ipò gíga fún ara wọn. Wọ́n lè sọ̀rọ̀ pẹlu ọpọlọpọ ìgboyà nípa igbagbọ tí ó wà ninu Kristi Jesu.
Explore TIMOTI KINNI 3:12-13
Home
Bible
Plans
Videos