Nígbà náà ni Isaaki, baba rẹ̀, dá a lóhùn, ó ní,
“Níbi tí ilẹ̀ kò ti lọ́ràá ni o óo máa gbé,
níbi tí kò sí ìrì ọ̀run.
Pẹlu idà rẹ ni o óo fi wà láàyè,
arakunrin rẹ ni o óo sì máa sìn,
ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, o óo já ara rẹ gbà,
o óo sì bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.”