1
AISAYA 1:18
Yoruba Bible
OLUWA ní, “Ẹ wá ná, ẹ jẹ́ kí á jọ sọ àsọyé pọ̀. Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ pọ́n bí iná, yóo di funfun bí ẹfun. Bí ó tilẹ̀ pupa bí aṣọ àlàárì, yóo di funfun bí irun ọmọ aguntan funfun.
Compare
Explore AISAYA 1:18
2
AISAYA 1:19
Bí ẹ bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́ràn, ẹ óo jẹ ire ilẹ̀ náà.
Explore AISAYA 1:19
3
AISAYA 1:17
Ẹ lọ kọ́ bí eniyan tí ń ṣe rere. Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́. Ẹ máa ran ẹni tí ara ń ni lọ́wọ́. Ẹ máa gbìjà aláìníbaba, kí ẹ sì máa gba ẹjọ́ opó rò.”
Explore AISAYA 1:17
4
AISAYA 1:20
Ṣugbọn tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ sì ṣoríkunkun; idà ni yóo run yín.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ.
Explore AISAYA 1:20
5
AISAYA 1:16
Ẹ wẹ̀, kí ara yín dá ṣáká. Ẹ má hùwà burúkú níwájú mi mọ́. Ẹ má ṣe iṣẹ́ ibi mọ́.
Explore AISAYA 1:16
6
AISAYA 1:15
“Bí ẹ bá tẹ́wọ́ adura, n óo gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ̀ báà tilẹ̀ gbadura, gbadura n kò ní gbọ́; nítorí ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀
Explore AISAYA 1:15
7
AISAYA 1:13
Ẹ má mú ẹbọ asán wá fún mi mọ́; ohun ìríra ni turari jẹ́ fún mi. Àjọ̀dún ìbẹ̀rẹ̀ oṣù titun, ọjọ́ ìsinmi, ati pípe àpéjọ. Ara mi kò gba ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dàpọ̀ mọ́ ẹ̀sìn mọ́.
Explore AISAYA 1:13
8
AISAYA 1:3
Mààlúù mọ olówó rẹ̀; kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sí mọ ibùjẹ tí oluwa rẹ̀ ṣe fún un; ṣugbọn Israẹli kò mọ nǹkan, òye kò yé àwọn eniyan mi.”
Explore AISAYA 1:3
9
AISAYA 1:14
Ninu ọkàn mi, mo kórìíra àwọn àjọ̀dún oṣù tuntun yín, ati àwọn àjọ̀dún pataki yín. Wọ́n ti di ẹrù wúwo fún mi, n kò lè gbé e mọ́, ó sú mi.
Explore AISAYA 1:14
Home
Bible
Plans
Videos