Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni èmi tíí sọ ohun tí ó gbẹ̀yìn.
Láti ìgbà àtijọ́,
ni mo tí ń sọ àwọn nǹkan tí kò ì tíì ṣẹlẹ̀.
Èmi a máa sọ pé: ‘Àbá mi yóo ṣẹ,
n óo sì mú ìpinnu mi ṣẹ.’
Mo pe idì láti ìlà oòrùn,
mo sì ti pe ẹni tí yóo mú àbá mi ṣẹ láti ilẹ̀ òkèèrè wá.
Mo ti sọ̀rọ̀, n óo sì mú un ṣẹ,
mo ti ṣe ìpinnu, n óo sì ṣe é.