1
AISAYA 51:12
Yoruba Bible
“Èmi fúnra mi ni mò ń tù ọ́ ninu, ta ni ọ́, tí o fi ń bẹ̀rù eniyan tí yóo kú? Ìwọ ń bẹ̀rù ọmọ eniyan tí a dá, bíi koríko.
Compare
Explore AISAYA 51:12
2
AISAYA 51:16
Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu, mo ti pa ọ́ mọ́ lábẹ́ òjìji ọwọ́ mi. Èmi ni mo fi ojú ọ̀run sí ipò rẹ̀, tí mo fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí mo sì sọ fún ìlú Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni eniyan mi.’ ”
Explore AISAYA 51:16
3
AISAYA 51:7
“Ẹ̀yin tí ẹ mọ òdodo, ẹ gbọ́ ohùn mi, ẹ̀yin tí ẹ fi tọkàntọkàn gba òfin mi, ẹ má bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn eniyan; ẹ má sì jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ wọn já a yín láyà.
Explore AISAYA 51:7
4
AISAYA 51:3
“OLUWA yóo tu Sioni ninu, yóo tu gbogbo àwọn tí ó ṣòfò ninu rẹ̀ ninu; yóo sì sọ aṣálẹ̀ rẹ̀ dàbí Edẹni, ọgbà OLUWA. Ayọ̀ ati ìdùnnú ni yóo máa wà ninu rẹ̀, pẹlu orin ọpẹ́ ati orin ayọ̀.
Explore AISAYA 51:3
5
AISAYA 51:11
Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada wá, pẹlu orin ni wọn óo pada wá sí Sioni. Adé ayọ̀ ni wọn óo dé sórí, wọn óo láyọ̀, inú wọn yóo dùn; ìbànújẹ́ ati ẹ̀dùn wọn yóo sì fò lọ.
Explore AISAYA 51:11
Home
Bible
Plans
Videos