“Bí ẹ bá dẹ́kun láti máa ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́,
tí ẹ kò sì máa ṣe ìfẹ́ inú yín lọ́jọ́ mímọ́ mi;
bí ẹ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ọjọ́ ìdùnnú,
tí ẹ pe ọjọ́ mímọ́ OLUWA ní ọjọ́ ológo;
bí ẹ bá yẹ́ ẹ sí, tí ẹ kò yà sí ọ̀nà tiyín,
tí ẹ kò máa ṣe ìfẹ́ inú ara yín,
tabi kí ẹ máa sọ̀rọ̀ àhesọ;
nígbà náà ni inú yín yóo máa dùn láti sin èmi OLUWA,
n óo gbe yín gun orí òkè ilẹ̀ ayé,
n óo sì mu yín jogún Jakọbu, baba ńlá yín.
Èmi OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.”