1
AISAYA 60:1
Yoruba Bible
Dìde, tan ìmọ́lẹ̀; nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, ògo OLUWA sì ti tàn sára rẹ.
Compare
Explore AISAYA 60:1
2
AISAYA 60:3
Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ, àwọn ọba yóo sì wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ tí ń tàn.
Explore AISAYA 60:3
3
AISAYA 60:2
Nítorí òkùnkùn yóo bo ayé mọ́lẹ̀, òkùnkùn biribiri yóo sì bo àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀, ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ OLUWA yóo tàn sára rẹ, ògo OLUWA yóo sì hàn lára rẹ.
Explore AISAYA 60:2
4
AISAYA 60:22
Ìdílé tí ó rẹ̀yìn jùlọ yóo di orílẹ̀-èdè, èyí tí ó sì kéré jùlọ yóo di orílẹ̀-èdè ńlá, Èmi ni OLUWA, kíákíá ni n óo ṣe é nígbà tí àkókò rẹ̀ bá tó.”
Explore AISAYA 60:22
5
AISAYA 60:19
“Kì í ṣe oòrùn ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe òṣùpá ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní òru: OLUWA ni yóo máa jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ, Ọlọrun rẹ yóo sì jẹ́ ògo rẹ.
Explore AISAYA 60:19
6
AISAYA 60:20
Oòrùn rẹ kò ní wọ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá rẹ kò ní wọ òkùnkùn. Nítorí OLUWA ni yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ, ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ yóo sì dópin.
Explore AISAYA 60:20
7
AISAYA 60:5
Nígbà tí o bá rí wọn, inú rẹ yóo dùn, ara rẹ óo yá gágá. Ọkàn rẹ yóo kún fún ayọ̀, nítorí pé a óo gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọrọ̀ inú òkun wá sọ́dọ̀ rẹ. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo kó ọrọ̀ wọn wá fún ọ.
Explore AISAYA 60:5
8
AISAYA 60:4
Gbé ojú sókè kí o wò yíká, gbogbo wọn kó ara wọn jọ, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ; àwọn ọmọ rẹ ọkunrin yóo wá láti òkèèrè, a óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin lé apá wá.
Explore AISAYA 60:4
9
AISAYA 60:21
Gbogbo àwọn eniyan rẹ yóo jẹ́ olódodo, àwọn ni yóo jogún ilẹ̀ náà títí lae. Àwọn ni ẹ̀ka igi tí mo gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi, kí á baà lè yìn mí lógo.
Explore AISAYA 60:21
10
AISAYA 60:18
Kò tún ní sí ìró ìdàrúdàpọ̀ ní ilẹ̀ rẹ mọ́, kò sì ní sí ìdágìrì ati ìparun ní ibodè rẹ, o óo máa pe odi rẹ ní ìgbàlà, o óo sì máa pe ẹnubodè rẹ ní ìyìn.
Explore AISAYA 60:18
11
AISAYA 60:11
Ṣíṣí ni ìlẹ̀kùn rẹ yóo máa wà nígbà gbogbo, a kò ní tì wọ́n tọ̀sán-tòru; kí àwọn eniyan lè máa kó ọrọ̀ orílẹ̀-èdè wá fún ọ, pẹlu àwọn ọba wọn tí wọn yóo máa tì siwaju.
Explore AISAYA 60:11
12
AISAYA 60:6
Ogunlọ́gọ̀ ràkúnmí yóo yí ọ ká, àwọn ọmọ ràkúnmí Midiani ati Efa. Gbogbo àwọn tí wọn wà ní Ṣeba yóo wá, wọn óo mú wúrà ati turari wá; wọn óo sì máa pòkìkí OLUWA.
Explore AISAYA 60:6
13
AISAYA 60:10
OLUWA ní, “Àwọn àjèjì ni yóo máa tún odi rẹ mọ, àwọn ọba wọn yóo sì máa ṣe iranṣẹ fún ọ; nítorí pé inú ló bí mi ni mo fi nà ọ́. Ṣugbọn nítorí ojurere mi ni mo fi ṣàánú fún ọ.
Explore AISAYA 60:10
14
AISAYA 60:15
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ̀ ọ́, wọ́n sì kórìíra rẹ, tí kò sí ẹni tí ń gba ààrin rẹ̀ kọjá mọ́, n óo sọ ọ́ di àmúyangàn títí lae; àní, ohun ayọ̀ láti ìrandíran.
Explore AISAYA 60:15
15
AISAYA 60:16
O óo mu wàrà àwọn orílẹ̀-èdè, o óo mu wàrà àwọn ọba. O óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni olùgbàlà rẹ, ati Olùràpadà rẹ, Ẹni Ńlá Jakọbu.
Explore AISAYA 60:16
Home
Bible
Plans
Videos