1
JOṢUA 1:9
Yoruba Bible
Ranti pé mo ti pàṣẹ fún ọ pé kí o múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn rẹ, nítorí pé èmi, OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ níbikíbi tí o bá ń lọ.”
Compare
Explore JOṢUA 1:9
2
JOṢUA 1:8
Máa ka ìwé òfin yìí nígbà gbogbo, kí o sì máa ṣe àṣàrò ninu rẹ̀, tọ̀sán-tòru; rí i dájú pé o pa gbogbo ohun tí wọ́n kọ sinu rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni yóo dára fún ọ, gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé yóo sì máa yọrí sí rere.
Explore JOṢUA 1:8
3
JOṢUA 1:7
Ìwọ ṣá ti múra, kí o ṣe ọkàn gírí, kí o sì rí i dájú pé o pa gbogbo òfin tí Mose, iranṣẹ mi, fún ọ mọ́. Má ṣe yẹsẹ̀ kúrò ninu rẹ̀ sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé níbikíbi tí o bá lọ lè máa yọrí sí rere.
Explore JOṢUA 1:7
4
JOṢUA 1:5
Kò ní sí ẹni tí yóo lè borí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Bí mo ti wà pẹlu Mose ni n óo wà pẹlu rẹ. N kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lae.
Explore JOṢUA 1:5
5
JOṢUA 1:6
Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, nítorí ìwọ ni o óo jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn, pé n óo fún wọn.
Explore JOṢUA 1:6
6
JOṢUA 1:3
Gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ yín bá tẹ̀ ni mo ti fun yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Mose.
Explore JOṢUA 1:3
7
JOṢUA 1:2
“Mose iranṣẹ mi ti kú, nítorí náà, ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ẹ múra kí ẹ la odò Jọdani kọjá, kí ẹ sì wọ ilẹ̀ tí n óo fun yín.
Explore JOṢUA 1:2
8
JOṢUA 1:1
Lẹ́yìn ikú Mose, iranṣẹ OLUWA, OLUWA sọ fún Joṣua, ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ Mose pé
Explore JOṢUA 1:1
9
JOṢUA 1:4
Láti inú aṣálẹ̀ ati òkè Lẹbanoni yìí lọ, títí dé odò ńlá náà, odò Yufurate, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Hiti, títí dé Òkun Mẹditarenia ní apá ìwọ̀ oòrùn, ni yóo jẹ́ ilẹ̀ yín.
Explore JOṢUA 1:4
10
JOṢUA 1:18
Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí àṣẹ rẹ, tí ó sì kọ̀ láti ṣe ohunkohun tí o bá sọ fún un, pípa ni a óo pa á. Ìwọ ṣá ti múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí.”
Explore JOṢUA 1:18
11
JOṢUA 1:11
“Ẹ lọ káàkiri ibùdó, kí ẹ sì pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, pé kí wọn máa pèsè oúnjẹ sílẹ̀, nítorí pé láàrin ọjọ́ mẹta wọn óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun wọn fún wọn.”
Explore JOṢUA 1:11
Home
Bible
Plans
Videos