1
ÌWÉ ÒWE 29:25
Yoruba Bible
Ìbẹ̀rù eniyan a máa di ìdẹkùn fún eniyan, ṣugbọn ẹni bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo wà láìléwu.
Compare
Explore ÌWÉ ÒWE 29:25
2
ÌWÉ ÒWE 29:18
Orílẹ̀-èdè tí kò bá ní ìfihàn láti ọ̀run, yóo dàrú, ṣugbọn ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń pa òfin mọ́.
Explore ÌWÉ ÒWE 29:18
3
ÌWÉ ÒWE 29:11
Òmùgọ̀ eniyan a máa bínú, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa mú sùúrù.
Explore ÌWÉ ÒWE 29:11
4
ÌWÉ ÒWE 29:15
Pàṣán ati ìbáwí a máa kọ́ ọmọ lọ́gbọ́n, ọmọ tí a bá fi sílẹ̀ yóo dójúti ìyá rẹ̀.
Explore ÌWÉ ÒWE 29:15
5
ÌWÉ ÒWE 29:17
Tọ́ ọmọ rẹ, yóo sì fún ọ ní ìsinmi, yóo sì mú inú rẹ dùn.
Explore ÌWÉ ÒWE 29:17
6
ÌWÉ ÒWE 29:23
Ìgbéraga eniyan a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ṣugbọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn yóo gba iyì.
Explore ÌWÉ ÒWE 29:23
7
ÌWÉ ÒWE 29:22
Ẹni tí inú ń bí a máa dá rògbòdìyàn sílẹ̀, onínúfùfù a sì máa ṣe ọpọlọpọ àṣìṣe.
Explore ÌWÉ ÒWE 29:22
8
ÌWÉ ÒWE 29:20
Òmùgọ̀ nírètí ju ẹni tí yóo sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀, tí kò lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu lọ.
Explore ÌWÉ ÒWE 29:20
Home
Bible
Plans
Videos