1
ORIN DAFIDI 40:1-2
Yoruba Bible
Sùúrù ni mo fi dúró de OLUWA, ó dẹ etí sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi. Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun, láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀; ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta, ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀.
Compare
Explore ORIN DAFIDI 40:1-2
2
ORIN DAFIDI 40:3
Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu, àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa. Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n, wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.
Explore ORIN DAFIDI 40:3
3
ORIN DAFIDI 40:4
Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà, tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA, tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn, àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa.
Explore ORIN DAFIDI 40:4
4
ORIN DAFIDI 40:8
mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi; mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.”
Explore ORIN DAFIDI 40:8
5
ORIN DAFIDI 40:11
Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA, sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́.
Explore ORIN DAFIDI 40:11
Home
Bible
Plans
Videos