1
I. Tim 6:12
Bibeli Mimọ
Mã jà ìja rere ti igbagbọ́, di ìye ainipẹkun mu ninu eyiti a gbé pè ọ si, ti iwọ si ṣe ijẹwo rere niwaju ẹlẹri pupọ̀.
Compare
Explore I. Tim 6:12
2
I. Tim 6:10
Nitori ifẹ owo ni gbòngbo ohun buburu gbogbo: eyiti awọn miran nlepa ti a si mu wọn ṣako kuro ninu igbagbọ́, nwọn si fi ibinujẹ pupọ̀ gún ara wọn li ọ̀kọ̀.
Explore I. Tim 6:10
3
I. Tim 6:6
Ṣugbọn iwa-bi-Ọlọrun pẹlu itẹlọrùn ère nla ni.
Explore I. Tim 6:6
4
I. Tim 6:7
Nitori a kò mu ohun kan wá si aiye, bẹni a kò si le mu ohunkohun jade lọ.
Explore I. Tim 6:7
5
I. Tim 6:17
Kìlọ fun awọn ti o lọrọ̀ li aiye isisiyi, ki nwọn máṣe gberaga, bẹni ki nwọn máṣe gbẹkẹle ọrọ̀ aidaniloju, bikoṣe le Ọlọrun alãye, ti nfi ohun gbogbo fun wa lọpọlọpọ lati lo
Explore I. Tim 6:17
6
I. Tim 6:9
Ṣugbọn awọn ti nfẹ di ọlọrọ̀ a mã bọ́ sinu idanwò ati idẹkun, ati sinu wère ifẹkufẹ pipọ ti ipa-ni-lara, iru eyiti imã rì enia sinu iparun ati ègbé.
Explore I. Tim 6:9
7
I. Tim 6:18-19
Ki nwọn ki o mã ṣõre, ki nwọn ki o mã pọ̀ ni iṣẹ rere, ki nwọn mura lati pin funni, ki nwọn ki o ni ẹmi ibakẹdun; Ki nwọn ki o mã tò iṣura ipilẹ rere jọ fun ara wọn dè igba ti mbọ̀, ki nwọn ki o le di ìye tõtọ mu.
Explore I. Tim 6:18-19
Home
Bible
Plans
Videos