Nigbati nwọn dé Mara, nwọn ko le mu ninu omi Mara, nitoriti o korò; nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Mara.
Awọn enia na si nkùn si Mose wipe, Kili awa o mu?
O si kepè OLUWA; OLUWA si fi igi kan hàn a, nigbati o si sọ ọ sinu omi na, omi si di didùn. Nibẹ̀ li o si gbé ṣe ofin ati ìlana fun wọn, nibẹ̀ li o si gbé dán wọn wò