1
Gẹn 50:20
Bibeli Mimọ
Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ibi li ẹnyin rò si mi; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọ si rere, lati mu u ṣẹ, bi o ti ri loni lati gbà ọ̀pọlọpọ enia là.
Compare
Explore Gẹn 50:20
2
Gẹn 50:19
Josefu si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: emi ha wà ni ipò Ọlọrun?
Explore Gẹn 50:19
3
Gẹn 50:21
Njẹ nisisiyi, ẹ má bẹ̀ru: emi o bọ́ nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin. O si tù wọn ninu, o si sọ̀rọ rere fun wọn.
Explore Gẹn 50:21
4
Gẹn 50:17
Bayi ni ki ẹnyin wi fun Josefu pe, Njẹ emi bẹ̀ ọ, dari irekọja ati ẹ̀ṣẹ awọn arakunrin rẹ jì wọn, nitori ibi ti nwọn ṣe si ọ. Njẹ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, dari irekọja awọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọn. Josefu si sọkun nigbati nwọn sọ fun u.
Explore Gẹn 50:17
5
Gẹn 50:24
Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi kú: Ọlọrun yio si bẹ̀ nyin wò nitõtọ, yio si mú nyin jade kuro ni ilẹ yi, si ilẹ ti o ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu.
Explore Gẹn 50:24
6
Gẹn 50:25
Josefu si mu awọn ọmọ Israeli bura, wipe, Ọlọrun yio bẹ̀ nyin wò nitõtọ, ki ẹnyin ki o si rù egungun mi lati ihin lọ.
Explore Gẹn 50:25
7
Gẹn 50:26
Bẹ̃ni Josefu kú, o jẹ́ ẹni ãdọfa ọdún: nwọn si kùn u li ọṣẹ, a si tẹ́ ẹ sinu posi ni Egipti.
Explore Gẹn 50:26
Home
Bible
Plans
Videos