1
Isa 54:17
Bibeli Mimọ
Kò si ohun-ijà ti a ṣe si ọ ti yio lè ṣe nkan; ati gbogbo ahọn ti o dide si ọ ni idajọ ni iwọ o da li ẹbi. Eyi ni ogún awọn iranṣẹ Oluwa, lati ọdọ mi ni ododo wọn ti wá, li Oluwa wi.
Compare
Explore Isa 54:17
2
Isa 54:10
Nitori awọn oke-nla yio ṣi lọ, a o si ṣi awọn oke kékèké ni idi, ṣugbọn ore mi kì yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni emi kì yio ṣi majẹmu alafia mi ni ipò: li Oluwa wi, ti o ṣãnu fun ọ.
Explore Isa 54:10
3
Isa 54:4
Má bẹ̀ru, nitori oju kì yio tì ọ: bẹ̃ni ki o máṣe dãmu; nitori a ki yio doju tì ọ; nitori iwọ o gbagbe itìju igbà ewe rẹ, iwọ kì yio sì ranti ẹ̀gan iwà-opo rẹ mọ.
Explore Isa 54:4
4
Isa 54:5
Nitori Ẹlẹda rẹ li ọkọ rẹ; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀; ati Olurapada rẹ Ẹni-Mimọ Israeli; Ọlọrun agbaiye li a o ma pè e.
Explore Isa 54:5
5
Isa 54:2
Sọ ibi agọ rẹ di gbigbõro, si jẹ ki wọn nà aṣọ tita ibugbe rẹ̀ jade: máṣe dási, sọ okùn rẹ di gigùn, ki o si mu ẽkàn rẹ le.
Explore Isa 54:2
6
Isa 54:13
A o si kọ́ gbogbo awọn ọmọ rẹ lati ọdọ Oluwa wá; alafia awọn ọmọ rẹ yio si pọ̀.
Explore Isa 54:13
7
Isa 54:8
Ni ṣiṣàn ibinu li emi pa oju mi mọ kuro lara rẹ ni iṣẹju kan! ṣugbọn õre ainipẹkun li emi o fi ṣãnu fun ọ; li Oluwa Olurapada rẹ wí.
Explore Isa 54:8
8
Isa 54:7
Ni iṣẹju diẹ ni mo ti kọ̀ ọ silẹ, ṣugbọn li ãnu nla li emi o kó ọ jọ
Explore Isa 54:7
9
Isa 54:9
Nitori bi awọn omi Noa li eyi ri si mi, nitori gẹgẹ bi mo ti bura pe omi Noa kì yio bò aiye mọ, bẹ̃ni mo si ti bura pe emi kì yio binu si ọ, bẹ̃ni emi kì yio ba ọ wi.
Explore Isa 54:9
10
Isa 54:12
Emi o fi rubi ṣe ṣonṣo-ile rẹ, emi o si fi okuta didán ṣe àsẹ rẹ; emi o si fi awọn okuta àṣayan ṣe agbègbe rẹ.
Explore Isa 54:12
Home
Bible
Plans
Videos