1
Joh 13:34-35
Bibeli Mimọ
Ofin titun kan ni mo fifun nyin, Ki ẹnyin ki o fẹ ọmọnikeji nyin; gẹgẹ bi emi ti fẹran nyin, ki ẹnyin ki o si le fẹran ọmọnikeji nyin. Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mọ̀ pe, ọmọ-ẹhin mi li ẹnyin iṣe, nigbati ẹnyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji nyin.
Compare
Explore Joh 13:34-35
2
Joh 13:14-15
Njẹ bi emi ti iṣe Oluwa ati Olukọni nyin ba wẹ̀ ẹsẹ nyin, o tọ́ ki ẹnyin pẹlu si mã wẹ̀ ẹsẹ ara nyin. Nitori mo ti fi apẹ̃rẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã ṣe gẹgẹ bi mo ti ṣe si nyin.
Explore Joh 13:14-15
3
Joh 13:7
Jesu dahùn o si wi fun u pe, Ohun ti emi nṣe iwọ kò mọ̀ nisisiyi; ṣugbọn yio ye ọ nikẹhin.
Explore Joh 13:7
4
Joh 13:16
Lòtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ; bẹ̃ni ẹniti a rán kò tobi jù ẹniti o rán a lọ.
Explore Joh 13:16
5
Joh 13:17
Bi ẹnyin ba mọ̀ nkan wọnyi, alabukun-fun ni nyin, bi ẹnyin ba nṣe wọn.
Explore Joh 13:17
6
Joh 13:4-5
O dide ni idi onjẹ alẹ, o si fi agbáda rẹ̀ lelẹ̀ li apakan; nigbati o si mu gèle, o di ara rẹ̀ li àmure. Lẹhinna o bù omi sinu awokòto kan, o si bẹ̀rẹ si ima wẹ̀ ẹsẹ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si nfi gèle ti o fi di àmure nù wọn.
Explore Joh 13:4-5
Home
Bible
Plans
Videos