1
Luk 13:24
Bibeli Mimọ
Ẹ làkaka lati wọ̀ oju-ọ̀na tõro: nitori mo wi fun nyin, enia pipọ ni yio wá ọ̀na ati wọ̀ ọ, nwọn kì yio si le wọle.
Compare
Explore Luk 13:24
2
Luk 13:11-12
Si kiyesi i, obinrin kan wà nibẹ̀ ti o ni ẹmí ailera, lati ọdún mejidilogun wá, ẹniti o tẹ̀ tan, ti ko le gbé ara rẹ̀ soke bi o ti wù ki o ṣe. Nigbati Jesu ri i, o pè e si ọdọ, o si wi fun u pe, Obinrin yi, a tú ọ silẹ lọwọ ailera rẹ.
Explore Luk 13:11-12
3
Luk 13:13
O si fi ọwọ́ rẹ̀ le e: lojukanna a si ti sọ ọ di titọ, o si nyìn Ọlọrun logo.
Explore Luk 13:13
4
Luk 13:30
Si wo o, awọn ẹni-ẹ̀hin mbẹ ti yio di ẹni-iwaju, awọn ẹni-iwaju mbẹ, ti yio di ẹni-ẹ̀hin.
Explore Luk 13:30
5
Luk 13:25
Nigbati bãle ile ba dide lẹkan fũ, ti o ba si ti sé ilẹkun, ẹnyin o si bẹ̀rẹ si iduro lode, ti ẹ o ma kànkun, wipe, Oluwa, Oluwa, ṣí i fun wa; on o si dahùn wi fun nyin pe, Emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá
Explore Luk 13:25
6
Luk 13:5
Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ.
Explore Luk 13:5
7
Luk 13:27
On o si wipe, Emi wi fun nyin, emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá; ẹ lọ kuro lọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ.
Explore Luk 13:27
8
Luk 13:18-19
O si wipe, Kini ijọba Ọlọrun jọ? kili emi o si fi wé? O dabi wóro irugbin mustardi, ti ọkunrin kan mú, ti o si sọ sinu ọgbà rẹ̀; ti o si hù, o si di igi nla; awọn ẹiyẹ oju ọrun si ngbé ori ẹká rẹ̀.
Explore Luk 13:18-19
Home
Bible
Plans
Videos