1
Mat 18:20
Bibeli Mimọ
Nitori nibiti ẹni meji tabi mẹta ba kó ara wọn jọ li orukọ mi, nibẹ̀ li emi o wà li ãrin wọn.
Compare
Explore Mat 18:20
2
Mat 18:19
Mo wi fun nyin ẹ̀wẹ pe, Bi ẹni meji ninu nyin ba fi ohùn ṣọkan li aiye yi niti ohunkohun ti nwọn o bère; a o ṣe e fun wọn lati ọdọ Baba mi ti mbẹ li ọrun wá.
Explore Mat 18:19
3
Mat 18:2-3
Jesu si pe ọmọ kekere kan sọdọ rẹ̀, o mu u duro larin wọn, O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, bikoṣepe ẹnyin ba pada, ki ẹ si dabi awọn ọmọ kekere, ẹnyin kì yio le wọle ijọba ọrun.
Explore Mat 18:2-3
4
Mat 18:4
Nitorina ẹnikẹni ti o ba rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ bi ọmọ kekere yi, on na ni yio pọ̀ju ni ijọba ọrun.
Explore Mat 18:4
5
Mat 18:5
Ẹniti o ba si gbà irú ọmọ kekere yi kan, li orukọ mi, o gbà mi
Explore Mat 18:5
6
Mat 18:18
Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba dè li aiye, a o dè e li ọrun, ohunkohun ti ẹnyin ba si tú li aiye, a o tú u li ọrun.
Explore Mat 18:18
7
Mat 18:35
Bẹ̃ na gẹgẹ ni Baba mi ti mbẹ li ọrun yio si ṣe fun nyin, bi olukuluku kò ba fi tọkàn-tọkan rẹ̀ dari ẹ̀ṣẹ arakunrin rẹ̀ jì i.
Explore Mat 18:35
8
Mat 18:6
Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi ti o gbà mi gbọ́ kọsẹ̀, o ya fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si rì i si ibú omi okun.
Explore Mat 18:6
9
Mat 18:12
Ẹnyin ti rò o si? bi ọkunrin kan ba ni ọgọrun agutan, bi ọkan nù ninu wọn, kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ̀, kì yio lọ sori òke lọ iwá eyi ti o nù bi?
Explore Mat 18:12
Home
Bible
Plans
Videos