1
Mak 5:34
Bibeli Mimọ
O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia, ki iwọ ki o si sàn ninu arun rẹ.
Compare
Explore Mak 5:34
2
Mak 5:25-26
Obinrin kan ti o ti ni isun ẹ̀jẹ li ọdún mejila, Ẹniti oju rẹ̀ si ri ohun pipọ lọdọ ọ̀pọ awọn oniṣegun, ti o si ti ná ohun gbogbo ti o ni tan, ti kò si sàn rara, ṣugbọn kàka bẹ̃ o npọ̀ siwaju.
Explore Mak 5:25-26
3
Mak 5:29
Lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ; on si mọ̀ lara rẹ̀ pe, a mu on larada ninu arun na.
Explore Mak 5:29
4
Mak 5:41
O si mu ọmọ na li ọwọ́, o wi fun u pe, Talita kumi; itumọ eyi ti ijẹ Ọmọbinrin, mo wi fun ọ, Dide.
Explore Mak 5:41
5
Mak 5:35-36
Bi o si ti nsọ̀rọ li ẹnu, awọn kan ti ile olori sinagogu wá ti o wipe, Ọmọbinrin rẹ kú: ẽṣe ti iwọ si fi nyọ olukọni lẹnu? Lojukanna bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ na ti a sọ, o si wi fun olori sinagogu na pe, Má bẹ̀ru, sá gbagbọ́ nikan.
Explore Mak 5:35-36
6
Mak 5:8-9
Nitoriti o wi fun u pe, Jade kuro lara ọkunrin na, iwọ ẹmi aimọ́. O si bi i lẽre pe, Orukọ rẹ? O si dahùn, wipe, Legioni li orukọ mi: nitori awa pọ̀.
Explore Mak 5:8-9
Home
Bible
Plans
Videos