1
Owe 15:1
Bibeli Mimọ
IDAHÙN pẹlẹ yi ibinu pada; ṣugbọn ọ̀rọ lile ni irú ibinu soke.
Compare
Explore Owe 15:1
2
Owe 15:33
Ibẹ̀ru Oluwa li ẹkọ́ ọgbọ́n; ati ṣãju ọlá ni irẹlẹ.
Explore Owe 15:33
3
Owe 15:4
Ahọn imularada ni igi ìye: ṣugbọn ayidayida ninu rẹ̀ ni ibajẹ ọkàn.
Explore Owe 15:4
4
Owe 15:22
Laisi ìgbimọ, èro a dasan; ṣugbọn li ọ̀pọlọpọ ìgbimọ, nwọn a fi idi mulẹ.
Explore Owe 15:22
5
Owe 15:13
Inu-didùn a mu oju daraya; ṣugbọn nipa ibinujẹ aiya, ọkàn a rẹ̀wẹsi.
Explore Owe 15:13
6
Owe 15:3
Oju Oluwa mbẹ ni ibi gbogbo, o nwò awọn ẹni-buburu ati ẹni-rere.
Explore Owe 15:3
7
Owe 15:16
Diẹ pẹlu ibẹ̀ru Oluwa, o san jù iṣura pupọ ti on ti iyọnu ninu rẹ̀.
Explore Owe 15:16
8
Owe 15:18
Abinu enia rú asọ̀ soke; ṣugbọn ẹniti o lọra ati binu, o tù ìja ninu.
Explore Owe 15:18
9
Owe 15:28
Aiya olododo ṣe àṣaro lati dahùn; ṣugbọn ẹnu enia buburu ngufẹ ohun ibi jade.
Explore Owe 15:28
Home
Bible
Plans
Videos