1
Ifi 3:20
Bibeli Mimọ
Kiyesi i, mo duro li ẹnu ilẹkun, mo si nkànkun, bi ẹnikẹni ba gbọ́ ohùn mi, ti o si ṣí ilẹkun, emi o si wọle tọ̀ ọ wá, emi o si ma ba a jẹun, ati on pẹlu mi.
Compare
Explore Ifi 3:20
2
Ifi 3:15-16
Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, pe iwọ kò gbóna bẹ̃ni iwọ kò tutù: emi iba fẹ pe ki iwọ kuku tutù, tabi ki iwọ kuku gbóna. Njẹ nitoriti iwọ ṣe ìlọ́wọwọ, ti o kò si gbóna, bẹni o kò tutù, emi o pọ̀ ọ jade kuro li ẹnu mi.
Explore Ifi 3:15-16
3
Ifi 3:19
Gbogbo awọn ti emi ba fẹ ni mo mbawi, ti mo si nnà: nitorina ni itara, ki o si ronupiwada.
Explore Ifi 3:19
4
Ifi 3:8
Emi mọ̀ iṣẹ rẹ: kiyesi i, mo gbé ilẹkun ti o sí kalẹ niwaju rẹ, ti kò si ẹniti o le tì ì: pe iwọ li agbara diẹ, iwọ si pa ọ̀rọ mi mọ́, iwọ kò si sẹ́ orukọ mi.
Explore Ifi 3:8
5
Ifi 3:21
Ẹniti o ba ṣẹgun li emi o fifun lati joko pẹlu mi lori itẹ́ mi, bi emi pẹlu ti ṣẹgun, ti mo si joko pẹlu Baba mi lori itẹ́ rẹ̀.
Explore Ifi 3:21
6
Ifi 3:17
Nitoriti iwọ wipe, Emi li ọrọ̀, emi si npọ̀ si i li ọrọ̀, emi kò si ṣe alaini ohunkohun; ti iwọ kò si mọ̀ pe, òṣi ni iwọ, ati àre, ati talakà, ati afọju, ati ẹni-ìhoho
Explore Ifi 3:17
7
Ifi 3:10
Nitoriti iwọ ti pa ọ̀rọ sũru mi mọ́, emi pẹlu yio pa ọ mọ́ kuro ninu wakati idanwo ti mbọ̀wa de ba gbogbo aiye, lati dán awọn ti ngbe ori ilẹ aiye wo.
Explore Ifi 3:10
8
Ifi 3:11
Kiyesi i, emi mbọ̀ nisisiyi: di eyiti iwọ ni mu ṣinṣin, ki ẹnikẹni ki o máṣe gbà ade rẹ.
Explore Ifi 3:11
9
Ifi 3:2
Mã ṣọra, ki o si fi ẹsẹ ohun ti o kù mulẹ, ti o ṣe tan lati kú: nitori emi kò ri iṣẹ rẹ ni pipé niwaju Ọlọrun.
Explore Ifi 3:2
Home
Bible
Plans
Videos