1
Eksodu 23:25-26
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀yin yóò sí máa sin OLúWA Ọlọ́run yin, òun yóò si bùsi oúnjẹ rẹ. Èmi yóò mú àìsàn kúrò láàrín rẹ. Oyún kò ní bàjẹ́ lára obìnrin kan, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan kì yóò yàgàn ni ilẹ̀ rẹ. Èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.
Compare
Explore Eksodu 23:25-26
2
Eksodu 23:20
“Kíyèsi èmi rán angẹli kan lọ ní iwájú rẹ, láti ṣọ́ ọ ni ọ̀nà àti láti mú ọ dé ibi ti mo ti pèsè sílẹ̀ fún.
Explore Eksodu 23:20
3
Eksodu 23:22
Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí ohùn rẹ̀ tí ẹ sì ṣe ohun gbogbo ti mo ní kí ẹ ṣe, èmi yóò jẹ́ ọ̀tá àwọn ọ̀tá yín. Èmi yóò sì fóòro àwọn tí ń fóòro yín.
Explore Eksodu 23:22
4
Eksodu 23:2-3
“Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀pọ̀ ènìyàn láti ṣe aburú. Nígbà tí ìwọ bá jẹ́rìí sí ẹjọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po nípa gbígbé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ènìyàn. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú sí tálákà nínú ẹjọ́ rẹ̀.
Explore Eksodu 23:2-3
5
Eksodu 23:1
“Ìwọ kò gbọdọ̀ tan ìròyìn èké kalẹ̀: Ìwọ kò gbọdọ̀ ran ènìyàn búburú lọ́wọ́ láti jẹ́rìí èké.
Explore Eksodu 23:1
Home
Bible
Plans
Videos