Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá,
láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá.
Mo wí pé: Ète mi yóò dúró,
àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.
Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá;
láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ.
Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò mú ṣẹ;
èyí tí mo ti gbèrò, òun ni èmi yóò ṣe.