1
Isaiah 54:17
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan, àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́ ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi. Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ OLúWA, èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,” ni OLúWA wí.
Compare
Explore Isaiah 54:17
2
Isaiah 54:10
Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá tí a sì ṣí àwọn òkè kékeré nídìí, Síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,” ni OLúWA, ẹni tí ó ṣíjú àánú wò ọ́ wí.
Explore Isaiah 54:10
3
Isaiah 54:4
“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́. Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù. Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ Ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́.
Explore Isaiah 54:4
4
Isaiah 54:5
Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ; a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
Explore Isaiah 54:5
5
Isaiah 54:2
Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i, fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i, má ṣe dá a dúró; sọ okùn rẹ di gígùn, mú òpó rẹ lágbára sí i.
Explore Isaiah 54:2
6
Isaiah 54:13
Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni OLúWA yóò kọ́, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.
Explore Isaiah 54:13
7
Isaiah 54:8
Ní ríru ìbínú. Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun Èmi yóò ṣíjú àánú wò ọ́,” ni OLúWA Olùdáǹdè rẹ wí.
Explore Isaiah 54:8
8
Isaiah 54:7
“Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò mú ọ padà wá.
Explore Isaiah 54:7
9
Isaiah 54:9
“Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Noa, nígbà tí mo búra pé àwọn omi Noa kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.
Explore Isaiah 54:9
10
Isaiah 54:12
Èmi yóò fi iyùn ṣe odi rẹ, àwọn ẹnu-ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún, àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye.
Explore Isaiah 54:12
Home
Bible
Plans
Videos