1
Isaiah 62:4
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́ tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro. Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfsiba, àti ilẹ̀ rẹ ní Beula; nítorí OLúWA yóò yọ́nú sí ọ àti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.
Compare
Explore Isaiah 62:4
2
Isaiah 62:6-7
Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jerusalẹmu; wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru. Ẹ̀yin tí ń ké pe OLúWA, ẹ má ṣe fúnrayín ní ìsinmi, àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmi títí tí yóò fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀ tí yóò sì fi ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé.
Explore Isaiah 62:6-7
3
Isaiah 62:3
Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ OLúWA, adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ.
Explore Isaiah 62:3
4
Isaiah 62:5
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwó bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwó Gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lórí rẹ.
Explore Isaiah 62:5
Home
Bible
Plans
Videos