Nígbà náà ni Jobu dìde, ó sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà wí pé:
“Ní ìhòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá,
ni ìhòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ.
OLúWA fi fún ni, OLúWA sì gbà á lọ,
ìbùkún ni fún orúkọ OLúWA.”
Nínú gbogbo èyí Jobu kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi òmùgọ̀ pe Ọlọ́run lẹ́jọ́.