1
Luku 13:24
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
“Ẹ làkàkà láti gba ojú ọ̀nà tóóró wọlé: nítorí mo wí fún yín, ènìyàn púpọ̀ ni yóò wá ọ̀nà láti wọ̀ ọ́, wọn kì yóò sì lè wọlé.
Compare
Explore Luku 13:24
2
Luku 13:11-12
Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà níbẹ̀ tí ó ní ẹ̀mí àìlera, láti ọdún méjì-dínlógún wá, ẹni tí ó tẹ̀ tán, tí kò le gbé ara rẹ̀ sókè bí ó ti wù kí ó ṣe. Nígbà tí Jesu rí i, ó pè é sí ọ̀dọ̀, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, a tú ọ sílẹ̀ lọ́wọ́ àìlera rẹ.”
Explore Luku 13:11-12
3
Luku 13:13
Ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ lé e: Lójúkan náà a sì ti sọ ọ́ di títọ́, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo.
Explore Luku 13:13
4
Luku 13:30
Sì wò ó, àwọn ẹni ẹ̀yìn ń bẹ tí yóò di ẹni iwájú, àwọn ẹni iwájú ń bẹ tí yóò di ẹni ẹ̀yìn.”
Explore Luku 13:30
5
Luku 13:25
Nígbà tí baálé ilé bá dìde lẹ́ẹ̀kan fùú, tí ó bá sí ti ìlẹ̀kùn, ẹ̀yin ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lóde, tí ẹ ó máa kan ìlẹ̀kùn, wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣí i fún wa!’ “Òun ó sì dáhùn wí fún yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mọ̀ yín.
Explore Luku 13:25
6
Luku 13:5
Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò ṣe pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.”
Explore Luku 13:5
7
Luku 13:27
“Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’
Explore Luku 13:27
8
Luku 13:18-19
Ó sì wí pé, “Kín ni ìjọba Ọlọ́run jọ? Kín ni èmi ó sì fiwé? Ó dàbí hóró musitadi, tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì sọ sínú ọgbà rẹ̀; tí ó sì hù, ó sì di igi ńlá; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé orí ẹ̀ka rẹ̀.”
Explore Luku 13:18-19
Home
Bible
Plans
Videos