1
Saamu 139:14
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi; ìyanu ní iṣẹ́ rẹ; èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
Compare
Explore Saamu 139:14
2
Saamu 139:23-24
Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí; dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi Kí ó sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburú kan bá wà nínú mi kí ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.
Explore Saamu 139:23-24
3
Saamu 139:13
Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi; ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
Explore Saamu 139:13
4
Saamu 139:16
ojú rẹ ti rí ohun ara mi nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé: àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí, ní ọjọ́ tí a dá wọn, nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
Explore Saamu 139:16
5
Saamu 139:1
OLúWA, ìwọ tí wádìí mi, ìwọ sì ti mọ̀ mí.
Explore Saamu 139:1
6
Saamu 139:7
Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ? Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?
Explore Saamu 139:7
7
Saamu 139:2
Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi, ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
Explore Saamu 139:2
8
Saamu 139:4
Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, kíyèsi i, OLúWA, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
Explore Saamu 139:4
9
Saamu 139:3
Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi, gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
Explore Saamu 139:3
Home
Bible
Plans
Videos