1
Saamu 91:2
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Èmi yóò sọ nípa ti OLúWA pé, “Òun ni ààbò àti odi mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.
Compare
Explore Saamu 91:2
2
Saamu 91:1
Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.
Explore Saamu 91:1
3
Saamu 91:15
Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn; èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú, èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un
Explore Saamu 91:15
4
Saamu 91:11
Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ
Explore Saamu 91:11
5
Saamu 91:4
Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí, àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò; òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.
Explore Saamu 91:4
6
Saamu 91:9-10
Nítorí ìwọ fi OLúWA ṣe ààbò rẹ, ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ. Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́ Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.
Explore Saamu 91:9-10
7
Saamu 91:3
Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.
Explore Saamu 91:3
8
Saamu 91:7
Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, ẹgbàárùn-ún ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ
Explore Saamu 91:7
9
Saamu 91:5-6
Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru, tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán, Tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn, tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.
Explore Saamu 91:5-6
Home
Bible
Plans
Videos