KỌRINTI KINNI 14
14
Ẹ̀bùn Èdè Àjèjì ati Ti Ìsọtẹ́lẹ̀
1Ẹ máa lépa ìfẹ́. Ṣugbọn ẹ tún máa tiraka láti ní Ẹ̀mí Mímọ́, pàápàá jùlọ, ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀. 2Nítorí ẹni tí ó bá ń fi èdè sọ̀rọ̀ kò bá eniyan sọ̀rọ̀, Ọlọrun ni ó ń bá sọ̀rọ̀. Nítorí pé kò sí ẹni tí ó gbọ́ ohun tí ó ń sọ. Ẹ̀mí ni ó gbé e tí ó fi ń sọ ohun àṣírí tí ó ń sọ tí kò yé eniyan. 3Ṣugbọn ẹni tí ó ń waasu ń bá eniyan sọ̀rọ̀ fún ìdàgbà ti ẹ̀mí, fún ìtùnú, ati ìwúrí. 4Ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ara rẹ̀ nìkan ni ó ń mú dàgbà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń waasu ń mú ìjọ dàgbà.
5Inú mi ìbá dún bí gbogbo yín bá lè máa fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ohun tí ìbá dùn mọ́ mi ninu jùlọ ni pé kí ẹ lè máa waasu. Ẹni tí ó ń waasu ju ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ lọ, àfi bí ó bá túmọ̀ ohun tí ó fi èdè àjèjì sọ, kí ìjọ lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ fún ìdàgbà ẹ̀mí. 6Ará, ǹjẹ́ bí mo bá wá sọ́dọ̀ yín, tí mò ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, anfaani wo ni mo ṣe fun yín? Kò sí, àfi bí mo bá ṣe àlàyé nípa ìfihàn, tabi ìmọ̀, tabi iwaasu, tabi ẹ̀kọ́ tí mo fi èdè àjèjì sọ.
7Bí àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí à ń fi kọ orin, bíi fèrè tabi dùùrù, kò bá dún dáradára, ta ni yóo mọ ohùn orin tí wọn ń kọ? 8Bí ohun tí fèrè ogun bá ń wí kò bá yé eniyan, ta ni yóo palẹ̀ mọ́ fún ogun? 9Bẹ́ẹ̀ gan-an ni tí ẹ bá ń lo èdè àjèjì, tí ẹ kò lo ọ̀rọ̀ tí ó yé eniyan, báwo ni eniyan yóo ṣe mọ ohun tí ẹ ń sọ? Afẹ́fẹ́ lásán ni ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ sí. 10Láìsí àní-àní, oríṣìíríṣìí èdè ni ó wà láyé, ṣugbọn kò sí èyí tí kò ní ìtumọ̀ ninu wọn. 11Nítorí náà, bí n kò bá gbọ́ èdè kan, mo di aláìgbédè lójú ẹni tí ó bá ń sọ èdè náà, òun náà sì di kògbédè lójú mi. 12Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu yín. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀ ń tiraka láti ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, ẹ máa wá àwọn ẹ̀bùn tí yóo mú ìjọ dàgbà.
13Ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ fi níláti gbadura fún ẹ̀bùn láti lè túmọ̀ rẹ̀. 14Bí mo bá ń fi èdè àjèjì gbadura, ẹ̀mí mi ni ó ń gbadura, ṣugbọn n kò lo òye ti inú ara mi nígbà náà. 15Kí ni kí á wá wí? N óo gbadura bí Ẹ̀mí bá ti darí mi, ṣugbọn n óo kọrin pẹlu òye. 16Bí o bá ń gbadura ọpẹ́ ní ọkàn rẹ, bí ẹnìkan bá wà níbẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ, báwo ni yóo ṣe lè ṣe “Amin” sí adura ọpẹ́ tí ò ń gbà nígbà tí kò mọ ohun tí ò ń sọ? 17Ọpẹ́ tí ò ń ṣe lè dára ṣugbọn kò mú kí ẹlòmíràn lè dàgbà.
18Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí mò ń sọ ọpọlọpọ èdè àjèjì ju gbogbo yín lọ. 19Ṣugbọn ninu ìjọ, ó yá mi lára kí n sọ ọ̀rọ̀ marun-un pẹlu òye kí n lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn, jù kí n sọ ọ̀rọ̀ kí ilẹ̀ kún ní èdè àjèjì lọ.
20Ará, ẹ má máa ṣe bí ọmọde ninu èrò yín. Ó yẹ kí ẹ dàbí ọmọde tí kò mọ ibi, ṣugbọn kí ẹ jẹ́ àgbàlagbà ninu èrò yín.
21Ninu Òfin, ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, Oluwa wí pé,
“N óo bá àwọn eniyan yìí sọ̀rọ̀
láti ẹnu àwọn eniyan tí ó ń sọ èdè àjèjì,
ati láti ẹnu àwọn àlejò.
Sibẹ wọn kò ní gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.”#Ais 28:11-12
22Àwọn èdè àjèjì yìí kì í ṣe àmì fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bíkòṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́.
23Nítorí náà, nígbà tí gbogbo ìjọ bá péjọ pọ̀ sí ibìkan náà, tí gbogbo yín bá ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, tí àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ, tabi àwọn alaigbagbọ bá wọlé, ǹjẹ́ wọn kò ní sọ pé ẹ̀ ń ṣiwèrè ni? 24Ṣugbọn bí gbogbo yín bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, bí ẹnìkan tí ó jẹ́ alaigbagbọ tabi ẹnìkan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ bá wọlé, yóo gbọ́ ohun tí ó jẹ́ ìbáwí ati ohun tí yóo mú un yẹ ara rẹ̀ wò ninu ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń sọ. 25Àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ ọkàn rẹ̀ yóo hàn kedere, ni yóo bá dojúbolẹ̀, yóo sì júbà Ọlọrun. Yóo sọ pé, “Dájúdájú Ọlọrun wà láàrin yín.”
Ẹ Ṣe Ohun Gbogbo Létòlétò
26Ará, kí ni kókó ohun tí à ń sọ? Nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀, bí ẹnìkan bá ní orin, tí ẹnìkan ní ẹ̀kọ́, tí ẹnìkan ní ìfihàn, tí ẹnìkan ní èdè àjèjì, tí ẹnìkan ní ìtumọ̀ fún èdè àjèjì, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ohun gbogbo fún ìdàgbà ìjọ. 27Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, kí wọ́n má ju meji lọ, tabi ó wá pọ̀jù patapata, kí wọ́n jẹ́ mẹta. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni kí wọ́n máa sọ̀rọ̀, kí ẹnìkan sì máa túmọ̀ ohun tí wọn ń sọ. 28Bí kò bá sí ẹni tí yóo ṣe ìtumọ̀, kí ẹni tí ó fẹ́ fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ dákẹ́ ninu ìjọ. Kí ó máa fi èdè àjèjì bá ara rẹ̀ ati Ọlọrun sọ̀rọ̀. 29Ẹni meji tabi mẹta ni kí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀, kí àwọn yòókù máa fi òye bá ohun tí wọn ń sọ lọ. 30Bí ẹlòmíràn tí ó jókòó ní àwùjọ bá ní ìfihàn, ẹni kinni tí ó ti ń sọ̀rọ̀ níláti dákẹ́. 31Gbogbo yín lè sọ àsọtẹ́lẹ̀, lọ́kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo yín lè rí ẹ̀kọ́ kọ́, kí gbogbo yín lè ní ìwúrí. 32Àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ níláti lè káwọ́ ara wọn nígbà tí ẹ̀mí bá gbé wọn láti sọ àsọtẹ́lẹ̀. 33Nítorí Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun ìdàrúdàpọ̀. Ọlọrun alaafia ni.
Ipò Obinrin ninu Ìsìn
Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ninu gbogbo ìjọ eniyan Ọlọrun, 34àwọn obinrin gbọdọ̀ panumọ́ ninu ìjọ. A kò gbà wọ́n láyè láti sọ̀rọ̀. Wọ́n níláti wà ní ipò ìtẹríba, gẹ́gẹ́ bí Òfin ti wí. 35Bí nǹkankan bá wà tí wọ́n fẹ́ mọ̀, kí wọ́n bi àwọn ọkọ wọn ní ilé. Ìtìjú ni fún obinrin láti sọ̀rọ̀ ninu ìjọ.
36Ṣé ọ̀dọ̀ yín ni ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti kọ́ bẹ̀rẹ̀ ni àbí ẹ̀yin nìkan ni ẹ mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọrun?
Gbolohun Ìparí Nípa Ètò Ìsìn
37Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé wolii ni òun tabi pé òun ní agbára Ẹ̀mí, kí olúwarẹ̀ mọ̀ pé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Oluwa ni ohun tí mo kọ ranṣẹ si yín yìí. 38Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni kò bá gba ohun tí a wí yìí, a kò gba òun náà.
39Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ máa tiraka láti sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ẹ má ka fífi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ sí èèwọ̀. 40Ẹ máa ṣe ohun gbogbo létòlétò, ní ọ̀nà tí ó dára.
Currently Selected:
KỌRINTI KINNI 14: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: