PETERU KINNI 3
3
Ọ̀rọ̀ fún Àwọn Ọkọ ati Aya
1Bákan náà ni kí ẹ̀yin aya máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkọ yín. Ìdí rẹ̀ ni pé bí a bá rí ninu àwọn ọkọ tí kò jẹ́ onigbagbọ, wọ́n lè yipada nípa ìwà ẹ̀yin aya wọn láìjẹ́ pé ẹ bá wọn sọ gbolohun kan nípa ẹ̀sìn igbagbọ,#Efe 5:22; Kol 3:18 2nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà mímọ́ ati ìwà ọmọlúwàbí yín. 3Ẹwà yín kò gbọdọ̀ jẹ́ ti òde ara nìkan bíi ti irun-dídì, ati nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí ẹ kó sára ati aṣọ-ìgbà.#1 Tim 2:9 4Ṣugbọn kí ẹwà yín jẹ́ ti ọkàn tí kò hàn sóde, ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Èyí ni ẹwà tí kò lè ṣá, èyí tí ó ṣe iyebíye lójú Ọlọrun. 5Nítorí ní ìgbà àtijọ́ irú ẹwà báyìí ni àwọn aya tí a yà sọ́tọ̀, àwọn tí wọ́n ní ìrètí ninu Ọlọrun, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Wọ́n bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn. 6Irú wọn ni Sara tí ó gbọ́ràn sí Abrahamu lẹ́nu tí ó pè é ní “Oluwa mi.” Ọmọ Sara ni yín, tí ẹ bá ń ṣe dáradára, tí ẹ kò jẹ́ kí nǹkankan bà yín lẹ́rù tabi kí ó mú ìpayà ba yín.#Jẹn 18:12
7Kí ẹ̀yin ọkọ náà máa fi ọgbọ́n bá àwọn aya yín gbé. Ẹ máa bu ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò lágbára to yín. Ẹ ranti pé wọ́n jẹ́ alábàápín ẹ̀bùn ìyè pẹlu yín. Tí ẹ bá ń ṣe èyí, kò ní sí ìdènà ninu adura yín.#Efe 5:25; Kol 3:19
Ìjìyà nítorí Òdodo
8Ní gbolohun kan, ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ ni ojú àánú. Ẹ ní ìfẹ́ sí ara yín. Ẹ máa ṣoore. Ẹ ní ọkàn ìrẹ̀lẹ̀. 9Ẹ má fi burúkú gbẹ̀san burúkú, tabi kí ẹ fi àbùkù kan ẹni tí ó bá fi àbùkù kàn yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ wọn ní rere ni. Irú ìwà tí a ní kí ẹ máa hù nìyí, kí ẹ lè jogún ibukun tí Ọlọrun ṣèlérí fun yín. 10Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,
“Ẹni tí ó bá fẹ́ ìgbé-ayé tí ó wù ú,
tí ó fẹ́ rí ọjọ́ tí ó dára,
ó níláti kó ara rẹ̀ ni ìjánu
pẹlu ọ̀rọ̀ burúkú sísọ,
kí ó má fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
11Ó níláti yipada kúrò ninu ìwà burúkú,
kí ó máa hu ìwà rere.
Ó níláti máa wá alaafia,
kí ó sì máa lépa rẹ̀.
12Nítorí Oluwa ń ṣọ́ àwọn olódodo,
ó sì dẹ etí sí ẹ̀bẹ̀ wọn.
Ṣugbọn ojú Oluwa kan sí
àwọn tí ó ń ṣe burúkú.”#O. Daf 34:12-16
13Ta ni lè ṣe yín ní ibi tí ẹ bá ní ìtara fún ohun tíí ṣe rere? 14Ṣugbọn bí ẹ bá tilẹ̀ jìyà nítorí òdodo, ẹ ṣe oríire. Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọn ń jẹ yín níyà, kí ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú.#Mat 5:10 15Ṣugbọn ẹ fi ààyè fún Kristi ninu ọkàn yín bí Oluwa. Ẹ múra nígbà gbogbo láti dáhùn bí ẹnikẹ́ni bá bi yín ní ìbéèrè nípa ìrètí tí ẹ ní.#Ais 8:12-13 16Ṣugbọn kí ẹ dáhùn pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní àìdára, ojú yóo ti àwọn tí wọn ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa yín, nígbà tí wọn bá rí ìgbé-ayé yín gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ. 17Nítorí ó sàn fun yín tí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun pé kí ẹ jìyà, nítorí pé ẹ̀ ń ṣe rere, jù pé ẹ̀ ń ṣe ibi lọ. 18Nítorí Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ wa; olódodo ni, ó kú fún alaiṣododo, kí ó lè mú wa wá sọ́dọ̀ Ọlọrun. A pa á ní ti ara, ṣugbọn ó wà láàyè ní ti ẹ̀mí. 19Nípa ẹ̀mí, ó lọ waasu fún àwọn ẹ̀mí tí ó wà lẹ́wọ̀n. 20Àwọn wọnyi ni ẹ̀mí àwọn ẹni tí kò gbàgbọ́ nígbà kan rí, nígbà ayé Noa, nígbà tí Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ mú sùúrù tí Noa fi kan ọkọ̀ tán. Ninu ọkọ̀ yìí ni àwọn eniyan díẹ̀ wà, àwọn mẹjọ, tí a fi gbà wọ́n là ninu ìkún omi.#Jẹn 6:1–7:24 21Èyí jẹ́ àkàwé ìrìbọmi tí ó ń gba eniyan là nisinsinyii. Kì í ṣe láti wẹ ìdọ̀tí kúrò lára, bíkòṣe ọ̀nà tí ẹ̀bẹ̀ eniyan fi lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọrun nípa ẹ̀rí ọkàn rere, nípa ajinde Jesu Kristi, 22ẹni tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, tí ó ti kọjá lọ sọ́run, lẹ́yìn tí àwọn angẹli ati àwọn aláṣẹ ati àwọn alágbára ojú ọ̀run ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.
Currently Selected:
PETERU KINNI 3: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: