SAMUẸLI KINNI 10
10
1Nígbà náà ni Samuẹli mú ìgò òróró olifi kan, ó tú u lé Saulu lórí. Ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì wí fún un pé, “OLUWA fi àmì òróró yàn ọ́ ní olórí àwọn eniyan Israẹli. Ohun tí yóo sì jẹ́ àmì tí o óo fi mọ̀ pé OLUWA ló yàn ọ́ láti jọba lórí àwọn eniyan rẹ̀ nìyí: 2Nígbà tí o bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi lónìí, o óo pàdé àwọn ọkunrin meji kan lẹ́bàá ibojì Rakẹli, ní Selisa, ní agbègbè Bẹnjamini. Wọn yóo sọ fún ọ pé, ‘Wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ẹ̀ ń wá. Nisinsinyii baba rẹ kò dààmú nítorí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́, ṣugbọn ó ń jáyà nítorí rẹ, ó ń wí pé, “Kí ni n óo ṣe nípa ọmọ mi.” ’ 3Nígbà tí o bá kúrò níbẹ̀, tí o sì ń lọ, o óo dé ibi igi oaku tí ó wà ní Tabori. O óo pàdé àwọn ọkunrin mẹta kan, tí wọ́n ń lọ rúbọ sí Ọlọrun ní Bẹtẹli. Ọ̀kan ninu wọn yóo fa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ mẹta lọ́wọ́, ekeji yóo kó burẹdi mẹta lọ́wọ́, ẹkẹta yóo sì gbé ìgò aláwọ kan tí ó kún fún ọtí waini lọ́wọ́. 4Wọn yóo kí ọ, wọn yóo sì fún ọ ní meji ninu burẹdi náà, gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn. 5Lẹ́yìn náà, lọ sí òkè Ọlọrun ní Gibea Elohimu, ní ibi tí ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini kan wà. Nígbà tí ó bá kù díẹ̀ kí ẹ dé ìlú náà, o óo pàdé ọ̀wọ́ àwọn wolii kan, tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ibi pẹpẹ tí ó wà ní orí òkè. Wọn yóo máa ta hapu, wọn yóo máa lu aro, wọn yóo máa fọn fèrè, wọn yóo máa tẹ dùùrù, wọn yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. 6Nígbà náà, ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé ọ, o óo sì darapọ̀ mọ́ wọn, o óo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, o óo sì yàtọ̀ patapata sí bí o ti wà tẹ́lẹ̀. 7Nígbà tí gbogbo nǹkan wọnyi bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ṣe ohunkohun tí ó bá wá sọ́kàn rẹ, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ. 8Máa lọ sí Giligali ṣiwaju mi. N óo wá bá ọ níbẹ̀ láti rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia. Dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ meje, títí tí n óo fi dé, n óo sì sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ.”
9Yíyí tí Saulu yipada kúrò lọ́dọ̀ Samuẹli, Ọlọrun sọ ọ́ di ẹ̀dá titun. Gbogbo àwọn àmì tí Samuẹli sọ fún un patapata ni ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà. 10Nígbà tí Saulu ati iranṣẹ rẹ̀ dé Gibea, ọ̀wọ́ àwọn wolii kan pàdé rẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ láàrin wọn. 11Nígbà tí àwọn tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i bí ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹlu àwọn wolii, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi? Àbí Saulu náà ti di wolii ni?” 12Ọkunrin kan tí ń gbé ibẹ̀ bèèrè pé, “Ta ni baba àwọn wolii wọnyi?” Láti ìgbà náà ni ó ti di àṣà kí àwọn eniyan máa wí pé, “Àbí Saulu náà ti di wolii ni?” 13Lẹ́yìn tí Saulu ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tán, ó lọ sí ibi pẹpẹ, ní orí òkè.#1 Sam 19:23-24
14Arakunrin baba rẹ̀ rí òun ati iranṣẹ rẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ ti lọ?”
Saulu dáhùn pé, “Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni a wá lọ. Nígbà tí a wá wọn tí a kò rí wọn, a lọ sọ́dọ̀ Samuẹli.”
15Arakunrin baba Saulu bá bi í pé, “Kí ni Samuẹli sọ fun yín?”
16Saulu dáhùn pé, “Ó sọ fún wa pé, dájúdájú, wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣugbọn Saulu kò sọ fún un pé, Samuẹli sọ fún òun pé òun yóo jọba.
Wọ́n Fi Ìhó Ayọ̀ Gba Saulu ní Ọba
17Samuẹli pe àwọn eniyan náà jọ siwaju OLUWA ní Misipa. 18Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Mo kó yín jáde wá láti Ijipti, mo gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati gbogbo àwọn eniyan yòókù tí wọn ń ni yín lára.’ 19Ṣugbọn nisinsinyii ẹ ti kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, Ọlọrun tí ó gbà yín kúrò lọ́wọ́ ìṣòro ati ìyọnu. Ẹ wí fún mi pé, ‘Yan ẹnìkan, tí yóo jọba lórí wa.’ Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tò kọjá níwájú OLUWA ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.”
20Nígbà náà ni, Samuẹli mú kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tò kọjá níwájú OLUWA, gègé sì mú ẹ̀yà Bẹnjamini. 21Lẹ́yìn náà Samuẹli mú kí àwọn ìdílé ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Bẹnjamini tò kọjá, gègé sì mú ìdílé Matiri. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé Matiri bẹ̀rẹ̀ sí tò kọjá, gègé sì mú Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣugbọn wọn kò rí i nígbà tí wọ́n wá a. 22Wọ́n bi OLUWA pé, “Àbí ọkunrin náà kò wá ni?”
OLUWA dá wọn lóhùn pé, “Ó ti farapamọ́ sí ààrin àwọn ẹrù.”
23Wọ́n sáré lọ mú un jáde láti ibẹ̀. Nígbà tí ó dúró láàrin wọn, kò sí ẹni tí ó ga ju èjìká rẹ̀ lọ ninu wọn. 24Samuẹli bá wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹni tí OLUWA yàn nìyí. Kò sí ẹnikẹ́ni láàrin wa tí ó dàbí rẹ̀.”
Gbogbo àwọn eniyan náà kígbe sókè pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.”
25Samuẹli ṣe àlàyé àwọn ẹ̀tọ́ ati iṣẹ́ ọba fún àwọn eniyan náà. Ó kọ àwọn àlàyé náà sinu ìwé kan, ó sì gbé e siwaju OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó ní kí olukuluku máa lọ sí ilé rẹ̀. 26Saulu náà bá pada lọ sí ilé rẹ̀ ní Gibea. Àwọn akọni ọkunrin bíi mélòó kan tí Ọlọrun ti fi sí ní ọkàn bá Saulu lọ. 27Ṣugbọn àwọn oníjàngbọ̀n kan dáhùn pé, “Báwo ni eléyìí ṣe lè gbà wá?” Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣugbọn Saulu kò sọ̀rọ̀.
Currently Selected:
SAMUẸLI KINNI 10: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: