YouVersion Logo
Search Icon

TIMOTI KINNI 4:7-10

TIMOTI KINNI 4:7-10 YCE

Má jẹ́ kí á bá ọ ní ìdí ìtàn àgbọ́sọ tí kò wúlò ati àwọn ìtànkítàn tí àwọn ìyá arúgbó fẹ́ràn. Ṣe ara rẹ yẹ fún ìgbé-ayé eniyan Ọlọrun. Eniyan a máa rí anfaani níwọ̀nba tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá ti ara, ṣugbọn anfaani ti ẹ̀mí kò lópin; nítorí ó ní anfaani ní ayé yìí, ó tún fún eniyan ní anfaani ti ayé tí ń bọ̀. Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, ó sì yẹ kí eniyan gbà á tọkàntọkàn. Ìdí tí a fi ń ṣe làálàá nìyí, tí a sì ń jìjàkadì, nítorí a gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo eniyan, pàápàá jùlọ ti àwọn onigbagbọ.