SAMUẸLI KEJI 4
4
Wọ́n Pa Iṣiboṣẹti
1Nígbà tí Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu gbọ́ pé wọ́n ti pa Abineri ní Heburoni, ẹ̀rù bà á gidigidi, ìdààmú sì bá gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. 2Iṣiboṣẹti ní àwọn ìjòyè meji kan, tí wọ́n jẹ́ aṣaaju fún àwọn tí wọ́n máa ń dánà káàkiri. Orúkọ ekinni ni Baana, ti ekeji sì ni Rekabu, ọmọ Rimoni, ará Beeroti, ti ẹ̀yà Bẹnjamini. (Ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ka Beeroti kún.) 3Àwọn ará Beeroti ti sá lọ sí Gitaimu, ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé títí di òní olónìí.
4Jonatani ọmọ Saulu ní ọmọkunrin kan, tí ó yarọ, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mẹfiboṣẹti. Ọmọ ọdún marun-un ni, nígbà tí wọ́n mú ìròyìn ikú Saulu ati ti Jonatani wá, láti ìlú Jesireeli; ni olùtọ́jú rẹ̀ bá gbé e sá kúrò. Ibi tí ó ti ń fi ìkánjú gbé ọmọ náà sá lọ, ó já ṣubú, ó sì fi bẹ́ẹ̀ yarọ.#2Sam 9:3
5Ní ọjọ́ kan, Rekabu ati Baana, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti, gbéra, wọ́n lọ sí ilé Iṣiboṣẹti, wọ́n débẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀sán, ní àkókò tí Iṣiboṣẹti ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́. 6Oorun ti gbé obinrin tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, tí ń fẹ́ ọkà lọ́wọ́ lọ, ó sùn lọ fọnfọn. Rekabu ati Baana bá rọra yọ́ wọlé. 7Nígbà tí wọ́n wọlé, wọ́n bá a níbi tí ó sùn sí lórí ibùsùn ninu yàrá rẹ̀, wọ́n lù ú pa, wọ́n sì gé orí rẹ̀. Wọ́n gbé orí rẹ̀, wọ́n gba ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru ọjọ́ náà rìn. 8Nígbà tí wọ́n dé Heburoni, wọ́n gbé orí rẹ̀ tọ Dafidi ọba lọ, wọ́n sì wí fún un pé, “Orí Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ọ̀tá rẹ, tí ó ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ nìyí; oluwa mi, ọba, OLUWA ti mú kí ó ṣeéṣe láti gbẹ̀san, lára Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀.”
9Ṣugbọn Dafidi dá wọn lóhùn pé, “OLUWA tí ó ti ń yọ mí ninu gbogbo ewu, ni mo fi búra pé, 10ẹni tí ó wá ròyìn ikú Saulu fún mi ní Sikilagi rò pé ìròyìn ayọ̀ ni òun mú wá fún mi, ṣugbọn mo ní kí wọn mú un kí wọ́n pa á. Ó jẹ èrè ìròyìn ayọ̀ rẹ̀, tí ó mú wá fún mi. 11Báwo ni yóo ti burú tó fún àwọn ẹni ibi, tí wọ́n pa aláìṣẹ̀ sórí ibùsùn ninu ilé rẹ̀? Ṣé n kò ní gbẹ̀san pípa tí ẹ pa á lára yín, kí n sì pa yín rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé?” 12Dafidi pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sì pa Rekabu ati Baana. Wọ́n gé ọwọ́ wọn, ati ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì so wọ́n kọ́ lẹ́bàá adágún tí ó wà ní Heburoni. Wọ́n gbé orí Iṣiboṣẹti, wọ́n sì sin ín sí ibojì Abineri ní Heburoni.#2Sam 1:1-16
Currently Selected:
SAMUẸLI KEJI 4: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: