YouVersion Logo
Search Icon

JOHANU KẸTA 1

1
Ìkíni
1Èmi, Alàgbà, ni mo kọ ìwé yìí sí ọ, Gaiyu olùfẹ́, ẹni tí mo fẹ́ràn nítòótọ́.#A. Apo 19:29; Rom 16:23; 1 Kọr 1:14
2Olùfẹ́, mo gbadura pé kí ó dára fún ọ ní gbogbo ọ̀nà ati pé kí o ní ìlera, gẹ́gẹ́ bí o ti ní ìlera ninu ẹ̀mí. 3Inú mi dùn nígbà tí àwọn arakunrin dé, tí wọ́n ròyìn rẹ pé o ṣe olóòótọ́ sí ọ̀nà òtítọ́, ati pé ò ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́. 4Ayọ̀ mi kì í lópin, nígbà tí mo bá gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́.
Àjọṣepọ̀
5Olùfẹ́, ohun rere ni ò ń ṣe fún àwọn arakunrin, bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ àlejò. 6Níwájú gbogbo ìjọ níhìn-ín wọ́n jẹ́rìí sí oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ ninu ìrìn àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ fún òṣìṣẹ́ Ọlọrun. 7Nítorí pé orúkọ Jesu ni ó mú wọn máa rin ìrìn àjò láì gba ohunkohun lọ́wọ́ àwọn alaigbagbọ. 8Ó yẹ kí á máa ran irú wọn lọ́wọ́ kí á lè jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu wọn ninu iṣẹ́ òtítọ́.
Diotirefe Lòdì sí Wa
9Mo kọ ìwé kan sí ìjọ ṣugbọn Diotirefe tí ó fẹ́ ipò aṣiwaju láàrin ìjọ kò gba ohun tí mo sọ. 10Nítorí náà, nígbà tí mo bá dé, n óo ranti àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ń ṣe, tí ó ń sọ ìsọkúsọ nípa mi. Kò fi ọ̀ràn mọ bẹ́ẹ̀; kò gba àwọn arakunrin tí wọ́n wá, àwọn tí wọ́n sì fẹ́ gbà wọ́n, kò jẹ́ kí wọ́n gbà wọ́n, ó tún fẹ́ yọ wọ́n kúrò ninu ìjọ!
Ọ̀rọ̀ Ìyànjú
11Olùfẹ́, má tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú, ṣugbọn tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere. Ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ẹni tí ó bá ń ṣe rere ti wá. Ẹni tí ó bá ń ṣe burúkú kò mọ Ọlọrun.
12Gbogbo eniyan ni wọ́n ń ròyìn Demeteriu ní rere. Òtítọ́ pàápàá ń jẹ́rìí rẹ̀. Èmi náà jẹ́rìí sí i, o sì mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí mi.
Ó Dìgbà Díẹ̀
13Mo ní ohun pupọ tí mo fẹ́ bá ọ sọ, ṣugbọn n kò fẹ́ kọ ọ́ sinu ìwé. 14Mo ní ìrètí ati rí ọ láìpẹ́, nígbà náà a óo lè jọ sọ̀rọ̀ lojukooju.
15Kí alaafia máa bá ọ gbé. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa níhìn-ín kí ọ. Bá wa kí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́kọ̀ọ̀kan.

Currently Selected:

JOHANU KẸTA 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in