YouVersion Logo
Search Icon

ẸKISODU 10:13-14

ẸKISODU 10:13-14 YCE

Mose bá gbé ọ̀pá rẹ̀, ó nà án sókè, sórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti. OLUWA bá mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ wá láti ìlà oòrùn, afẹ́fẹ́ náà fẹ́ sórí gbogbo ilẹ̀ náà, ní gbogbo ọ̀sán ati ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Nígbà tí yóo fi di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, afẹ́fẹ́ ti kó eṣú dé. Eṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, wọ́n sì bà sí gbogbo ilẹ̀. Wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé irú rẹ̀ kò sí rí, irú rẹ̀ kò sì tún tíì ṣẹlẹ̀ mọ́ láti ìgbà náà.

Free Reading Plans and Devotionals related to ẸKISODU 10:13-14