YouVersion Logo
Search Icon

ẸKISODU 16:3-4

ẸKISODU 16:3-4 YCE

wọ́n ń wí pé, “Ìbá sàn kí OLUWA pa wá sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí olukuluku wa ti jókòó ti ìsaasùn ọbẹ̀ ẹran, tí a sì ń jẹ oúnjẹ àjẹyó, ju bí ẹ ti kó wa wá sí ààrin aṣálẹ̀ yìí lọ, láti fi ebi pa gbogbo wa kú.” OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Wò ó, n óo rọ̀jò oúnjẹ fún yín láti ọ̀run. Kí àwọn eniyan máa jáde lọ ní ojoojumọ, kí wọ́n sì máa kó ìwọ̀nba ohun tí wọn yóo jẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. N óo fi èyí dán wọn wò, kí n fi mọ̀ bóyá wọn yóo máa tẹ̀lé òfin mi tabi wọn kò ní tẹ̀lé e.