ẸKISODU 22
22
Òfin nípa Sísan Ẹ̀san
1“Bí ẹnìkan bá jí akọ mààlúù kan tabi aguntan kan gbé, tí ó bá pa á, tabi tí ó tà á, yóo san akọ mààlúù marun-un dípò ẹyọ kan ati aguntan mẹrin dípò aguntan kan. Tí kò bá ní ohun tí yóo fi tán ọ̀ràn náà, wọn yóo ta òun fúnra rẹ̀ láti san ohun tí ó jí. 2Bí a bá ká olè mọ́ ibi tí ó ti ń fọ́lé lóru, tí a sì lù ú pa, ẹni tí ó lù ú pa kò jẹ̀bi. 3Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ pé lojumọmọ ni, ẹ̀bi wà fún ẹni tí ó lù ú pa. Ṣugbọn tí ọwọ́ bá tẹ olè lojumọmọ, ó níláti san ohun tí ó jí pada. 4Bí wọ́n bá ká ẹran ọ̀sìn tí olè jí gbé mọ́ ọn lọ́wọ́ láàyè, kì báà ṣe akọ mààlúù, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tabi aguntan; ìlọ́po meji ni yóo fi san pada.
5“Bí ẹnìkan bá jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ jẹ oko olóko, tabi ọgbà àjàrà ẹlòmíràn, tabi tí ó bá da ẹran wọ inú oko olóko tí wọ́n sì jẹ nǹkan ọ̀gbìn inú rẹ̀, ibi tí ó dára jùlọ ninu oko tabi ọgbà àjàrà tirẹ̀ ni yóo fi dí i fún ẹni tí ó ni oko tabi ọgbà àjàrà tí ẹran rẹ̀ jẹ.
6“Bí ẹnìkan bá dáná, tí iná náà bá ràn mọ́ koríko, tí ó bá jó oko olóko, tí ó sì jó ọkà tí wọ́n ti kórè jọ tabi tí ó wà lóòró, olúwarẹ̀ gbọdọ̀ san òmíràn pada fún olóko.
7“Bí ẹnìkan bá fi owó tabi ìṣúra kan pamọ́ sí ọwọ́ aládùúgbò rẹ̀, tí olè bá gbé e lọ mọ́ aládùúgbò rẹ̀ yìí lọ́wọ́, bí ọwọ́ bá tẹ olè yìí, ìlọ́po meji ohun tí ó gbé ni yóo fi san. 8Bí ọwọ́ kò bá wá tẹ olè, ẹni tí ó gba ìṣúra pamọ́ yìí gbọdọ̀ wá sí ilé Ọlọrun kí ó fi Ọlọrun ṣẹ̀rí pé òun kò fi ọwọ́ kan ìṣúra tí aládùúgbò òun fi pamọ́ sí òun lọ́wọ́.
9“Nígbàkúùgbà tí ohun ìní bá di àríyànjiyàn láàrin eniyan meji, kì báà jẹ́ mààlúù, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tabi aguntan, tabi aṣọ, tabi ohunkohun tí ó bá ti sọnù, tí ó sì di àríyànjiyàn, àwọn mejeeji tí wọn ń lọ́ nǹkan mọ́ ara wọn lọ́wọ́ gbọdọ̀ wá sí ilé Ọlọrun, kí wọ́n sì fi Ọlọrun ṣẹ̀rí, ẹni tí Ọlọrun bá dá lẹ́bi yóo san ìlọ́po meji nǹkan náà fún ẹnìkejì rẹ̀.
10“Bí ẹnìkan bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní ẹran sìn, kì báà ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi mààlúù, tabi aguntan, bí ẹran náà bá kú tabi kí ó farapa, tabi tí ó bá rìn lọ tí kò sì sí ẹni tí ó rí i, 11aládùúgbò náà yóo lọ sí ilé Ọlọrun, yóo sì fi OLUWA ṣẹ̀rí pé òun kọ́ ni òun jí ẹran tí wọn fún òun sìn. Ẹni tí ó fún un ní ẹran sìn yóo faramọ́ ìbúra yìí, kò sì ní gbẹ̀san mọ́. 12Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé wọ́n jí i gbé mọ́ ọn lọ́wọ́ ni, yóo san ẹ̀san fún ẹni tí ó ni ín. 13Bí ó bá jẹ́ pé ẹranko burúkú ni ó pa á, bí ó bá ní ohun tí ó lè fi ṣe ẹ̀rí, tí ó sì fi ohun náà han ẹni tí ó ni ẹran náà, kò ní san ẹ̀san ẹran náà pada.
14“Bí ẹnìkan bá yá ẹran ọ̀sìn kẹ́ran ọ̀sìn lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀, tí ẹran náà bá farapa tabi tí ó kú, tí kò sì sí olówó ẹran náà níbẹ̀, ẹni tí ó yá ẹran náà níláti san án pada. 15Ṣugbọn bí ẹni tí ó ni ẹran náà bá wà níbẹ̀ nígbà tí ó kú, ẹni tí ó yá a kò ní san ẹ̀san pada. Bí ó bá jẹ́ pé owó ni wọ́n fi yá ẹran náà lọ tí ó fi kú, a jẹ́ pé orí iṣẹ́ owó rẹ̀ ni ó kú sí.
Òfin nípa Ìwà ati Ẹ̀sìn
16“Bí ẹnìkan bá tan wundia tí kì í ṣe àfẹ́sọ́nà ẹnikẹ́ni, tí ó sì bá wundia náà lòpọ̀, ó gbọdọ̀ san owó orí rẹ̀ kí ó sì gbé e níyàwó. 17Bí baba wundia náà bá kọ̀ jálẹ̀ pé òun kò ní fi ọmọ òun fún un, yóo san iye owó tí wọ́n bá ń san ní owó orí wundia tí kò mọ ọkunrin. #Diut 22:28-29
18“Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àjẹ́ wà láàyè. #Diut 18:10-11
19“Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹranko lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa á. #Lef 18:23; 20:15-16; Diut 27:21.
20“Ẹnikẹ́ni tí ó bá rúbọ sí oriṣa-koriṣa kan lẹ́yìn OLUWA, píparun ni kí wọ́n pa á run. #Diut 17:2-7.
21“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ pọ́n àlejò lójú tabi kí ó ni ín lára, nítorí pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti. 22Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fìyà jẹ opó tabi aláìníbaba. #Eks 23:9; Lef 19:33-34; Diut 24:17-18; 27:19. 23Bí ẹnikẹ́ni bá fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n bá ké pè mí, dájúdájú n óo gbọ́ igbe wọn; 24ibinu mi yóo sì ru sí yín, n óo fi idà pa yín, àwọn aya yín yóo di opó, àwọn ọmọ yín yóo sì di aláìníbaba.
25“Bí o bá yá ẹnikẹ́ni lówó ninu àwọn eniyan mi, tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ, tí ó ṣe aláìní, má ṣe bí àwọn tí wọn ń fi owó wọn gba èlé, má gba èlé lórí owó tí o yá a. #Lef 25:35-38; Diut 15:7-11; 23:19-20. 26Bí aládùúgbò rẹ bá fi ẹ̀wù rẹ̀ dógò lọ́dọ̀ rẹ, tí o sì gbà á, dá a pada fún un kí oòrùn tó wọ̀; 27nítorí pé ẹ̀wù yìí ni àwọ̀lékè kan ṣoṣo tí ó ní, òun kan náà sì ni aṣọ ìbora rẹ̀. Àbí aṣọ wo ni ó tún ní tí yóo fi bora sùn? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ké pè mí, n óo dá a lóhùn, nítorí pé aláàánú ni mí. #Diut 24:10-13
28“O kò gbọdọ̀ kẹ́gàn Ọlọrun, o kò sì gbọdọ̀ gbé ìjòyè àwọn eniyan rẹ ṣépè. #A. Apo 23:5
29“O kò gbọdọ̀ jáfara láti mú ninu ọpọlọpọ ọkà rẹ ati ọpọlọpọ ọtí waini rẹ láti fi rúbọ sí mi.
“O níláti fún mi ní àkọ́bí rẹ ọkunrin pẹlu. 30Bákan náà ni àkọ́bí mààlúù rẹ ati ti aguntan rẹ, tí wọ́n bá jẹ́ akọ. Fi wọ́n sílẹ̀ pẹlu ìyá wọn fún ọjọ́ meje, ní ọjọ́ kẹjọ o níláti fi wọ́n rúbọ sí mi.
31“Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí a yà sọ́tọ̀ fún mi, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ òkú ẹran tí ẹranko bá pa ninu ìgbẹ́, ajá ni kí ẹ gbé irú ẹran bẹ́ẹ̀ fún. #Lef 17:15.
Currently Selected:
ẸKISODU 22: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: