ẸKISODU 8
8
1Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún Mose pé, “Lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, kí o sì wí fún un pé, ‘OLUWA ní, “Jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ sìn mí. 2Ṣugbọn bí o bá kọ̀, tí o kò jẹ́ kí wọ́n lọ, n óo da ọ̀pọ̀lọ́ bo ilẹ̀ rẹ. 3Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóo máa gbá yìnìn ninu odò Naili, wọn yóo sì wọ inú ààfin rẹ ati yàrá tí ò ń sùn, wọn yóo gun orí ibùsùn rẹ, wọn yóo sì wọ ilé àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati ti àwọn eniyan rẹ. N óo dà wọ́n sinu ilé ìdáná ati sinu àwo tí wọ́n fi ń tọ́jú oúnjẹ. 4Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà yóo máa fò mọ́ ìwọ, ati àwọn eniyan rẹ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ.” ’ ”
5OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni pé kí ó na ọwọ́ rẹ̀ ati ọ̀pá rẹ̀ sórí àwọn odò ati àwọn adágún tí wọ́n gbẹ́, ati sórí gbogbo ibi tí omi dárogún sí, kí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ lè jáde sórí ilẹ̀ Ijipti.” 6Aaroni bá na ọwọ́ rẹ̀ sí orí gbogbo omi ilẹ̀ Ijipti, ọ̀pọ̀lọ́ bá wọ́ jáde, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti. 7Àwọn pidánpidán náà ṣe bẹ́ẹ̀ pẹlu ọgbọ́n idán wọn, wọ́n mú kí ọ̀pọ̀lọ́ bo ilẹ̀ Ijipti.
8Nígbà náà ni Farao pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Ẹ bẹ OLUWA kí ó kó ọ̀pọ̀lọ́ kúrò lọ́dọ̀ èmi ati àwọn eniyan mi, n óo sì jẹ́ kí àwọn ará Israẹli lọ rúbọ sí OLUWA.”
9Mose dá Farao lóhùn pé, “Sọ ìgbà tí o fẹ́ kí n gbadura fún ìwọ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati àwọn eniyan rẹ, kí Ọlọrun lè run gbogbo àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí wọ́n wà lọ́dọ̀ yín, ati ninu ilé yín; kí ó sì jẹ́ pé kìkì odò Naili nìkan ni ọ̀pọ̀lọ́ yóo kù sí.”
10Ọba dáhùn pé, “Ní ọ̀la.”
Mose bá wí pé, “Bí o ti wí gan-an ni yóo rí, kí o lè mọ̀ pé kò sí ẹlòmíràn tí ó dàbí OLUWA Ọlọrun wa. 11Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà yóo kúrò lọ́dọ̀ rẹ, ati ninu àwọn ilé rẹ, ati lọ́dọ̀ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati lọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ; kìkì odò Naili nìkan ni ọ̀pọ̀lọ́ yóo kù sí.” 12Mose ati Aaroni bá jáde kúrò níwájú Farao, Mose gbadura sí OLUWA pé kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà kúrò, gẹ́gẹ́ bí òun ati Farao ti jọ ṣe àdéhùn. 13OLUWA ṣe ohun tí Mose fi adura bèèrè, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí wọ́n wà ninu gbogbo ilé, ati ní àgbàlá, ati ní gbogbo oko sì kú. 14Wọ́n kó wọn jọ ní òkítì òkítì, gbogbo ìlú sì bẹ̀rẹ̀ sí rùn. 15Nígbà tí Farao rí i pé gbogbo ọ̀pọ̀lọ́ náà kú tán, ọkàn rẹ̀ tún le, kò sì ṣe ohun tí Mose ati Aaroni wí mọ́, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.
Iná Orí Bo Ilẹ̀
16OLUWA rán Mose pé, kí ó sọ fún Aaroni pé kí ó na ọ̀pá rẹ̀ jáde, kí ó sì fi lu erùpẹ̀ ilẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ sì di iná orí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. 17Wọ́n ṣe bí OLUWA ti wí; Aaroni na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀, ó fi lu erùpẹ̀ ilẹ̀, iná sì bo àwọn eniyan ati àwọn ẹranko; gbogbo erùpẹ̀ ilẹ̀ sì di iná ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.
18Àwọn pidánpidán náà gbìyànjú láti mú kí iná jáde pẹlu ọgbọ́n idán wọn, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é. Iná bo gbogbo eniyan ati àwọn ẹranko. 19Àwọn pidánpidán náà sọ fún Farao pé, “Iṣẹ́ Ọlọrun ni èyí.” Ṣugbọn ọkàn Farao le, kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.#Luk 11:20
Eṣinṣin Bo Ilẹ̀
20OLUWA bá tún sọ fún Mose pé, “Dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, kí o lọ dúró de ọba Farao bí ó bá ti ń jáde lọ sétí odò, wí fún un pé, kí ó gbọ́ ohun tí èmi OLUWA wí, pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ sìn mí. 21Wí fún un pé, mo ní, tí kò bá jẹ́ kí wọ́n lọ n óo da eṣinṣin bo òun ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀, àwọn ará ilé rẹ̀ ati ti àwọn ará Ijipti, orí ilẹ̀ tí wọ́n dúró lé yóo sì kún fún ọ̀wọ́ eṣinṣin. 22Ṣugbọn ní ọjọ́ náà, èmi OLUWA yóo ya ilẹ̀ Goṣeni sọ́tọ̀, níbi tí àwọn eniyan mi ń gbé, kí ọ̀wọ́ eṣinṣin má baà lè débẹ̀, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA ní ayé yìí. 23Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi ààlà sí ààrin àwọn eniyan mi ati àwọn eniyan rẹ̀. Ní ọ̀la ni iṣẹ́ ìyanu náà yóo ṣẹ.” 24OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀; ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ inú ilé Farao ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Ijipti. Eṣinṣin sì ba ilẹ̀ náà jẹ́.
25Farao bá pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Ẹ lọ rúbọ sí Ọlọrun yín, ṣugbọn ní ilẹ̀ yìí ni kí ẹ ti rú u.”
26Mose dá a lóhùn pé, “Kò ní tọ̀nà bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀; nítorí pé àwọn nǹkan mìíràn lè wà ninu ohun tí a óo fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa tí ó lè jẹ́ ìríra fún àwọn ará Ijipti. Bí a bá fi ohunkohun rúbọ tí ó jẹ́ ìríra lójú àwọn ará Ijipti, ṣé wọn kò ní sọ wá ní òkúta pa? 27A níláti lọ sinu aṣálẹ̀ ní ìrìn ọjọ́ mẹta kí á sì rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún wa.”
28Farao dáhùn, ó ní, “N óo fún yín láàyè láti lọ rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín ninu aṣalẹ̀, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ lọ jìnnà; ati pé, mo fẹ́ kí ẹ bá mi bẹ Ọlọrun yín.”
29Mose bá dáhùn pé, “Wò ó, ń óo jáde kúrò ní iwájú rẹ nisinsinyii, n óo sì lọ gbadura sí OLUWA, kí ọ̀wọ́ eṣinṣin wọnyi lè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀la, kí wọ́n sì kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ ati àwọn eniyan rẹ pẹlu ṣugbọn kí Farao má tún dalẹ̀, kí ó má wí pé àwọn eniyan Israẹli kò gbọdọ̀ lọ rúbọ sí OLUWA.”
30Mose bá jáde kúrò níwájú Farao, ó lọ gbadura sí OLUWA, 31OLUWA sì ṣe ohun tí Mose bèèrè, ó mú kí ọ̀wọ́ eṣinṣin náà kúrò lọ́dọ̀ Farao ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀. Ó mú kí gbogbo eṣinṣin náà kúrò láìku ẹyọ kan. 32Ṣugbọn ọkàn Farao tún le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ.
Currently Selected:
ẸKISODU 8: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: