AISAYA 52
52
Ọlọrun Yóo Gba Jerusalẹmu
1Jí, Sioni, jí!#Ifi 21:2, 27
Gbé agbára rẹ wọ̀ bí aṣọ,
gbé ẹwà rẹ wọ̀ bí ẹ̀wù,
ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́;
nítorí àwọn aláìkọlà ati aláìmọ́, kò ní wọ inú rẹ mọ́.
2Dìde, gbọnranù kúrò ninu erùpẹ̀,
ìwọ Jerusalẹmu tí ó wà ninu ìdè.
Tú okùn tí a dè mọ́ ọ lọ́rùn kúrò,
ìwọ Sioni tí ó wà ninu ìdè.
3Nítorí OLUWA ní, “Ọ̀fẹ́ ni a mu yín lẹ́rú, ọ̀fẹ́ náà sì ni a óo rà yín pada. 4Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn eniyan mi lọ ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Ijipti, lẹ́yìn náà, àwọn ará Asiria pọ́n wọn lójú láì nídìí. 5Ṣugbọn nisinsinyii, kí ni mo rí yìí? Wọ́n mú àwọn eniyan mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn alákòóso wọn ń pẹ̀gàn, orúkọ mi wá di nǹkan yẹ̀yẹ́? 6Nítorí náà àwọn eniyan mi yóo mọ orúkọ mi, wọn óo sì mọ̀ ní ọjọ́ náà pé, èmi tí mò ń sọ̀rọ̀, èmi náà nìyí.”#Rom 2:24
7Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìyìn rere bọ̀ ti dára tó lórí òkè,#Neh 1:15; Rom 10:15 Efe 6:15
ẹni tí ń kéde alaafia,
tí ń mú ìyìn rere bọ̀,
tí sì ń kéde ìgbàlà,
tí ń wí fún Sioni pé,
“Ọlọrun rẹ jọba.”
8Gbọ́, àwọn aṣọ́de rẹ gbóhùn sókè,
gbogbo wọn jọ ń kọrin ayọ̀,
nítorí wọ́n jọ fi ojú ara wọn rí i,
tí OLUWA pada dé sí Sioni.
9Ẹ jọ máa kọrin pọ̀,
gbogbo ilẹ̀ Jerusalẹmu tí a sọ di aṣálẹ̀,
nítorí OLUWA yóo tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu,
yóo ra Jerusalẹmu pada.
10OLUWA yóo lo agbára mímọ́ rẹ̀, lójú àwọn orílẹ̀-èdè,
gbogbo eniyan, títí dé òpin ayé, yóo sì rí ìgbàlà Ọlọrun wa.
11Ẹ jáde, ẹ jáde ẹ kúrò níbẹ̀,#2 Kọr 6:17
ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan,
ẹ jáde kúrò láàrin rẹ̀, kí ẹ sì wẹ ara yín mọ́,
ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò OLUWA.
12Nítorí pé ẹ kò ní fi ìkánjú jáde,
bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní sáré jáde.
Nítorí OLUWA yóo máa lọ níwájú yín,
Ọlọrun Israẹli yóo sì wà lẹ́yìn yín.
Iranṣẹ tí Ń Jìyà
13Wò ó! Iranṣẹ mi yóo ṣe àṣeyọrí
a óo gbé e ga, a óo gbé e lékè;
yóo sì di ẹni gíga,
14Ẹnu ti ya ọpọlọpọ eniyan nítorí rẹ̀.
Wọ́n bà á lójú jẹ́ yánnayànna,
tóbẹ́ẹ̀ tí ìrísí rẹ̀ kò fi jọ ti eniyan mọ́.
15Bẹ́ẹ̀ ni yóo di ohun ìyanu fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè,#Rom 15:21
kẹ́kẹ́ yóo pamọ́ àwọn ọba wọn lẹ́nu,
nígbà tí wọ́n bá rí i,
wọn óo rí ohun tí wọn kò gbọ́ rí nípa rẹ̀,
òye ohun tí wọn kò mọ̀ rí yóo yé wọn.
Currently Selected:
AISAYA 52: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010