JOBU 14
14
1“Ẹnikẹ́ni tí obinrin bá bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni,
ó sì kún fún ìpọ́njú.
2Yóo kọ́ yọ bí òdòdó, lẹ́yìn náà yóo sì rẹ̀ dànù.
Yóo kọjá lọ bí òjìji, kò sì ní sí mọ́.#Ọgb 2:1; Sir 40:1-11; 41:1-4
3Ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni o dojú kọ,
tí ò ń bá ṣe ẹjọ́?
4Ta ló lè mú ohun mímọ́ jáde
láti inú ohun tí kò mọ́?
Kò sí ẹni náà.
5Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá ọjọ́ fún un,
tí o mọ iye oṣù rẹ̀,
tí o sì ti pa ààlà tí kò lè rékọjá.
6Mú ojú rẹ kúrò lára rẹ̀, kí ó lè sinmi,
kí ó sì lè gbádùn ọjọ́ ayé rẹ̀ bí alágbàṣe.
7“Nítorí pé ìrètí ń bẹ fún igi tí wọn gé,
yóo tún pada rúwé,
ẹ̀ka rẹ̀ kò sì ní ṣe aláìsọ.
8Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ògbólógbòó ninu ilẹ̀,
tí kùkùté rẹ̀ sì kú,
9bí ó bá ti gbóòórùn omi, yóo sọ,
yóo sì yọ ẹ̀ka bí ọ̀dọ́ irúgbìn.
10Ṣugbọn bí eniyan bá kú, a óo tẹ́ ẹ sinu ibojì,
bí ó bá ti gbẹ́mìí mì, ó di aláìsí.
11Bí adágún omi tíí gbẹ,
ati bí odò tíí ṣàn lọ, tí sìí gbẹ,
12bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe é sùn,
tí kì í sìí jí mọ́,
títí tí ọ̀run yóo fi kọjá lọ, kò ní jí,
tabi kí ó tilẹ̀ rúnra láti ojú oorun.
13Ìbá sàn kí o fi mí pamọ́ sinu ibojì,
kí o pa mí mọ́ títí inú rẹ yóo fi rọ̀,
ò bá dá àkókò fún mi, kí o sì ranti mi.
14Bí eniyan bá kú, ǹjẹ́ yóo tún jí mọ́?
N óo dúró ní gbogbo ọjọ́ làálàá mi,
n óo máa retí, títí ọjọ́ ìdáǹdè mi yóo fi dé.
15O óo pè mí, n ó sì dá ọ lóhùn,
o óo máa ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
16Nígbà náà, o óo máa tọ́ ìṣísẹ̀ mi,
o kò sì ní ṣọ́ àwọn àṣìṣe mi.
17O óo di àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi sinu àpò,
o óo sì bo àwọn àìdára mi mọ́lẹ̀.
18“Ṣugbọn òkè ńlá ṣubú, ó sì rún wómúwómú,
a sì ṣí àpáta nídìí kúrò ní ipò rẹ̀.
19Bí omi ṣe é yìnrìn òkúta,
tí àgbàrá sì í wọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀ lọ,
bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe sọ ìrètí eniyan di òfo.
20O ṣẹgun rẹ̀ títí lae, ó sì kọjá lọ,
o yí àwọ̀ rẹ̀ pada, o sì mú kí ó lọ.
21Wọ́n dá àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́lá, ṣugbọn kò mọ̀,
a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, sibẹ kò rí i.
22Ìrora ara rẹ̀ nìkan ló mọ̀,
ọ̀fọ̀ ara rẹ̀ nìkan ni ó ń ṣe.”
Currently Selected:
JOBU 14: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010