JOBU 17
17
1“Ọkàn mi bàjẹ́, ọjọ́ ayé mi ti dópin,
ibojì sì ń dúró dè mí.
2Dájúdájú àwọn ẹlẹ́yà yí mi káàkiri,
wọ́n ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ lojukooju.
3Fi nǹkan ẹ̀jẹ́ kan lélẹ̀ fún mi lọ́dọ̀ rẹ;
ta ló wà níbẹ̀ tí yóo ṣe onídùúró fún mi?
4Níwọ̀n ìgbà tí o ti mú ọkàn wọn yigbì sí ìmọ̀,
nítorí náà, o kò ní jẹ́ kí wọ́n borí.
5Bí ẹnìkan bá hùwà ọ̀dàlẹ̀, tí ó ṣòfófó àwọn ọ̀rẹ́,
kí ó lè pín ninu ohun ìní wọn,
àwọn ọmọ olúwarẹ̀ yóo jìyà.
6O ti sọ mí di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn eniyan,
mo di ẹni tí à ń tutọ́ sí lára.
7Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,
gbogbo ẹ̀yà ara mi dàbí òjìji.
8Èyí ya àwọn olódodo lẹ́nu,
aláìlẹ́bi sì dojú kọ ẹni tí kò mọ Ọlọrun.
9Sibẹsibẹ olódodo kò fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,
ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ sì ń lágbára sí i.
10Ṣugbọn ní tiyín, bí ẹ tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ,
n kò ní ka ẹnikẹ́ni kún ọlọ́gbọ́n láàrin yín.
11“Ọjọ́ ayé mi ti dópin, èrò ọkàn mi ti dàrú,
àwọn ohun tí ọkàn mi ń fẹ́ sì ti di asán.
12Wọ́n sọ òru di ọ̀sán,
wọ́n ń sọ pé, ‘Ìmọ́lẹ̀ kò jìnnà sí òkùnkùn.’
13Bí mo bá ní ìrètí pé ibojì yóo jẹ́ ilé mi,
tí mo tẹ́ ibùsùn mi sinu òkùnkùn,
14bí mo bá pe isà òkú ní baba,
tí mo sì pe ìdin ní ìyá tabi arabinrin mi,
15níbo ni ìrètí mi wá wà?
Ta ló lè rí ìrètí mi?
16Ṣé yóo lọ sí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ni?
Ṣé àwa mejeeji ni yóo jọ wọ inú erùpẹ̀ lọ?”
Currently Selected:
JOBU 17: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010