YouVersion Logo
Search Icon

JOBU 21

21
1Jobu dáhùn pé,
2“Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáradára,
kí ẹ sì jẹ́ kí ó jẹ́ ìtùnú fun yín.
3Ẹ farabalẹ̀, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,
lẹ́yìn náà, ẹ lè máa fi mí ṣẹ̀sín ǹṣó.
4Ṣé eniyan ni mò ń bá rojọ́ ni?
Kí ló dé tí n óo fi mú sùúrù?
5Ẹ wò mí, kí ẹnu yà yín,
kí ẹ sì fọwọ́ bo ẹnu.
6Nígbà tí mo ro ohun tí ó dé bá mi,
ẹ̀rù bà mí, mo sì wárìrì.
7Kí ló dé tí eniyan burúkú fi wà láàyè,
tí ó di arúgbó, tí ó sì di alágbára?
8Àwọn ọmọ wọn ati arọmọdọmọ wọn
di eniyan pataki pataki lójú ayé wọn.
9Kò sí ìfòyà ninu ilé wọn,
bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò jẹ wọ́n níyà.
10Àwọn mààlúù wọn ń gùn,
wọ́n sì ń bímọ ní àbíyè.
11Wọn a máa kó àwọn ọmọ wọn jáde bí agbo ẹran,
àwọn ọmọ wọn a sì máa ṣe àríyá.
12Wọn a máa fi aro, ìlù, ati fèrè kọrin,
wọn a sì máa yọ̀ sí ohùn dùùrù.
13Wọn a máa gbé inú ọlá,
wọn a sì máa kú ikú alaafia.
14Wọ́n ń sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀!
A kò fẹ́ mọ òfin rẹ.
15Ta ni Olodumare, tí a óo fi máa sìn ín?
Èrè wo ni ó wà níbẹ̀ fún wa bí à ń gbadura sí i?’
16Wọ́n rò pé ìkáwọ́ wọn ni ọlà wọn wà,
nítèmi n kò lè tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.
17“Ìgbà mélòó ni à ń pa fìtílà ẹni ibi?
Ìgbà mélòó ni iṣẹ́ ibi wọn ń dà lé wọn lórí?
Tabi tí Ọlọrun ṣe ìpín wọn ní ìrora ninu ibinu rẹ̀?
18Ìgbà mélòó ni wọ́n dàbí àgékù koríko,
tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri,
tabi bí ìyàngbò tí ìjì ń gbé lọ?
19“O ní, ‘Ọlọrun ń to àìdára wọn jọ de àwọn ọmọ wọn.’
Jẹ́ kí ó dà á lé wọn lórí, kí wọ́n baà lè mọ ohun tí wọ́n ṣe.
20Jẹ́ kí wọ́n fi ojú ara wọn rí ìparun ara wọn,
kí wọ́n sì rí ibinu Olodumare.
21Kí ni ó kàn wọ́n pẹlu ilé wọn mọ́, lẹ́yìn tí wọn bá ti kú,
nígbà tí a bá ti ké ọjọ́ wọn kúrò lórí ilẹ̀.
22Ṣé ẹnìkan lè kọ́ Ọlọrun ní ìmọ̀,
nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni onídàájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní ibi gíga?
23Ẹnìkan kú ninu ọpọlọpọ ọrọ̀,
nítorí pé ó wà ninu ìdẹ̀ra ati àìfòyà,
24ara rẹ̀ ń dán fún sísanra,
ara sì tù ú dé mùdùnmúdùn.
25Ẹlòmíràn kú pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn,
láìtọ́ ohun rere kankan wò rí.
26Bákan náà ni gbogbo wọn ṣe sùn ninu erùpẹ̀,
tí ìdin sì bò wọ́n.
27“Wò ó! Mo mọ èrò ọkàn yín,
mo sì mọ ète tí ẹ ní sí mi láti ṣe mí níbi.
28Nítorí ẹ wí pé, ‘Níbo ni ilé àwọn eniyan ńlá wà;
níbo sì ni àgọ́ àwọn aṣebi wà?’
29Ṣé ẹ kò tíì bèèrè ọ̀nà lọ́wọ́ àwọn arìnrìnàjò?
Ṣé ẹ kò sì tíì gba ẹ̀rí wọn, pé,
30a dá ẹni ibi sí ní ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀,
ati pé a gbà á là ní ọjọ́ ibinu?
31Kò sẹ́ni tó jẹ́ fẹ̀sùn kan ẹni ibi lójú rẹ̀,
tabi kí ó gbẹ̀san nǹkan burúkú tí ó ṣe.
32Nígbà tí a bá gbé e lọ sí itẹ́,
àwọn olùṣọ́ a máa ṣọ́ ibojì rẹ̀.
33Ẹgbẹẹgbẹrun èrò a tẹ̀lé e lọ sí ibojì,
àìmọye eniyan a sì sin òkú rẹ̀;
kódà, ilẹ̀ á dẹ̀ fún un ní ibojì rẹ̀.
34Nítorí náà, kí ni ìsọkúsọ tí ẹ lè fi tù mí ninu?
Kò sóhun tó kù ninu ọ̀rọ̀ yín,
tó ju irọ́ lọ.”

Currently Selected:

JOBU 21: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in