JOBU 27
27
1Jobu tún dáhùn pé,
2“Mo fi Ọlọrun tí ó gba ẹ̀tọ́ mi búra,
mo fi Olodumare tí ó mú kí ọkàn mi bàjẹ́ ṣẹ̀rí,
3níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè,
tí mo sì ń mí,
4n kò ní fi ẹnu mi purọ́,
ahọ́n mi kò sì ní sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
5Kí á má rí i, n kò jẹ́ pè yín ní olóòótọ́;
títí di ọjọ́ ikú mi ni n óo dúró lórí ọ̀rọ̀ mi,
pé mo wà lórí àre.
6Mo dúró lórí òdodo mi láìyẹsẹ̀,
ọkàn mi kò ní dá mi lẹ́bi,
títí n óo fi kú.
7“Kí ó rí fún ọ̀tá mi gẹ́gẹ́ bí í ti í rí fún ẹni ibi,
kí ó sì rí fún ẹni tí ó dojú kọ mí bí í ti í rí fún alaiṣododo.
8Ìrètí wo ni ẹni tí kò mọ Ọlọrun ní nígbà tí Ọlọrun bá pa á run,
tí Ọlọrun sì gba ẹ̀mí rẹ̀?
9Ǹjẹ́ Ọlọrun yóo gbọ́ igbe rẹ̀,
nígbà tí ìyọnu bá dé bá a?
10Ǹjẹ́ yóo ní inú dídùn sí Olodumare?
Ǹjẹ́ yóo máa ké pe Ọlọrun nígbà gbogbo?
11“N óo kọ yín ní ìmọ̀ agbára Ọlọ́run;
n kò sì ní fi ohun tíí ṣe ti Olodumare pamọ́.
12Wò ó! Gbogbo yín ni ẹ ti fojú yín rí i,
kí ló wá dé tí gbogbo yín fí ń sọ ìsọkúsọ?”
13“Ìpín ẹni ibi láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìyí,
òun ni ogún tí àwọn aninilára ń rí gbà lọ́dọ̀ Olodumare:
14Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá ń pọ̀ sí i,
kí ogun baà lè pa wọ́n ni,
oúnjẹ kò sì ní ká wọn lẹ́nu.
15Àwọn ọmọ tí wọn bá gbẹ̀yìn rẹ̀,
àjàkálẹ̀ àrùn ni yóo pa wọ́n,
àwọn opó wọn kò sì ní ṣọ̀fọ̀ wọn.
16Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń kó fadaka jọ bí erùpẹ̀,
tí ó sì to aṣọ jọ bí amọ̀;
17olódodo ni yóo wọ aṣọ tí ó bá kó jọ,
àwọn aláìṣẹ̀ ni yóo pín fadaka rẹ̀.
18Ilé tí ó kọ́ dàbí òwú aláǹtakùn,
àní bí àgọ́ àwọn tí wọn ń ṣọ́nà.
19A ti máa wọlé sùn pẹlu ọrọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn kò ní rí bẹ́ẹ̀ fún un mọ́.
Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ yóo ti fò lọ.
20Ìwárìrì á bò ó mọ́lẹ̀ bí ìkún omi,
ní alẹ́, ìjì líle á gbé e lọ.
21Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn á fẹ́ ẹ sókè,
á sì gbé e lọ,
á gbá a kúrò ní ipò rẹ̀.
22Á dìgbò lù ú láìṣàánú rẹ̀,
á sá lọ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.
23Ọlọrun á pàtẹ́wọ́ lé e lórí,
á sì pòṣé sí i láti ibi tí ó wà.
Currently Selected:
JOBU 27: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010