JOBU 30
30
1“Ṣugbọn nisinsinyii àwọn tí wọ́n kéré sí mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà,
àwọn tí baba wọn kò tó fi wé àwọn ajá
tí ń ṣọ́ agbo ẹran mi.
2Kí ni anfaani agbára wọn fún mi,
àwọn tí wọn kò lókun ninu?
3Ninu ìyà ati ebi,
wọ́n ń jẹ gbòǹgbò igi gbígbẹ káàkiri lálẹ́ ninu aṣálẹ̀.
4Ewé igi inú igbó ni wọ́n ń já jẹ,
àní, àwọn igi ọwọ̀ tí kò ládùn kankan.
5Wọ́n lé wọn jáde láàrin àwọn eniyan,
wọ́n ń hó lé wọn lórí bí olè.
6Wọ́n níláti máa gbé ojú àgbàrá,
ninu ihò ilẹ̀, ati ihò àpáta.
7Wọ́n ń dún bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ninu igbó,
wọ́n ń kó ara wọn jọ sí abẹ́ igi ẹlẹ́gùn-ún.
8Àwọn aláìlóye ọmọ,
àwọn ọmọ eniyan lásán,
àwọn tí a ti nà kúrò lórí ilẹ̀ náà.
9“Nisinsinyii mo ti di orin lẹ́nu wọn,
mo ti di àmúpòwe.
10Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn,
wọ́n ń rí mi sá,
ara kò tì wọ́n láti tutọ́ sí mi lójú.
11Nítorí Ọlọrun ti sọ mí di aláìlera,
ó sì ti rẹ̀ mí sílẹ̀,
wọn dojú ìjà kọ mí ninu ibinu wọn.
12Àwọn oníjàgídíjàgan dìde sí mi ní apá ọ̀tún mi,
wọ́n lé mi kúrò,
wọ́n sì la ọ̀nà ìparun sílẹ̀ fún mi.
13Wọ́n dínà mọ́ mi,
wọ́n dá kún wahala mi,
kò sì sí ẹni tí ó lè dá wọn lẹ́kun.
14Wọ́n jálù mí, bí ìgbà tí ọpọlọpọ ọmọ ogun bá gba ihò ara odi ìlú wọlé,
wọ́n ya lù mí, wọ́n wó mi mọ́lẹ̀.
15Ìbẹ̀rù-bojo dé bá mi,
wọ́n ń lépa ọlá mi bí afẹ́fẹ́,
ọlà mi sì parẹ́ bí ìkùukùu.
16“Nisinsinyii, ẹ̀mí mi fò lọ ninu mi,
ọjọ́ ìjìyà sì dé bá mi.
17Ní òru, egungun ń ro mí,
ìrora mi kò sì dínkù.
18Ọlọrun fi ipá gba aṣọ mi,
ó fún mi lọ́rùn bí ọrùn ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ mi.
19Ó sọ mí sinu ẹrẹ̀,
mo dàbí eruku ati eérú.
20“Mo ké pè ọ́, Ọlọrun, O kò dáhùn,
mo dìde dúró, mo gbadura, o kò kà mí sí.
21O dojú ibinu kọ mí,
o fi agbára rẹ bá mi jà.
22O sọ mí sókè ninu afẹ́fẹ́,
ò ń bì mí síhìn-ín sọ́hùn-ún
láàrin ariwo ìjì líle.
23Dájúdájú mo mọ̀ pé o óo gbé mi lọ sí ipò òkú,
ilé tí o yàn fún gbogbo eniyan.
24Bí ẹni tí a ti là mọ́lẹ̀, tí kò lè dìde, bá ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ninu ìnira,
dájúdájú o kò tún ní gbé ìjà kò ó?
25Ṣebí mo ti sọkún nítorí àwọn tí wọ́n wà ninu ìṣòro rí,
tí mo sì káàánú àwọn aláìní.
26Ṣugbọn nígbà tí mo bá ń retí ohun rere,
ibi ní ń bá mi.
Nígbà tí mo bá sì ń retí ìmọ́lẹ̀,
òkùnkùn ni mò ń rí.
27Ọkàn mi dàrú, ara mi kò balẹ̀,
ọjọ́ ìpọ́njú dé bá mi.
28Mo fa ojú ro, mò ń káàkiri,
mo dìde nàró láti bèèrè ìrànlọ́wọ́ láàrin àwùjọ.
29Mò ń kígbe arò bí ajáko,
mo di ẹgbẹ́ ẹyẹ ògòǹgò.
30Àwọ̀ ara mi di dúdú, ó ń bó,
egungun mi gbóná fún ooru.
31Ọ̀fọ̀ dípò orin ayọ̀ fún mi,
ẹkún sì dípò ohùn fèrè.
Currently Selected:
JOBU 30: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
JOBU 30
30
1“Ṣugbọn nisinsinyii àwọn tí wọ́n kéré sí mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà,
àwọn tí baba wọn kò tó fi wé àwọn ajá
tí ń ṣọ́ agbo ẹran mi.
2Kí ni anfaani agbára wọn fún mi,
àwọn tí wọn kò lókun ninu?
3Ninu ìyà ati ebi,
wọ́n ń jẹ gbòǹgbò igi gbígbẹ káàkiri lálẹ́ ninu aṣálẹ̀.
4Ewé igi inú igbó ni wọ́n ń já jẹ,
àní, àwọn igi ọwọ̀ tí kò ládùn kankan.
5Wọ́n lé wọn jáde láàrin àwọn eniyan,
wọ́n ń hó lé wọn lórí bí olè.
6Wọ́n níláti máa gbé ojú àgbàrá,
ninu ihò ilẹ̀, ati ihò àpáta.
7Wọ́n ń dún bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ninu igbó,
wọ́n ń kó ara wọn jọ sí abẹ́ igi ẹlẹ́gùn-ún.
8Àwọn aláìlóye ọmọ,
àwọn ọmọ eniyan lásán,
àwọn tí a ti nà kúrò lórí ilẹ̀ náà.
9“Nisinsinyii mo ti di orin lẹ́nu wọn,
mo ti di àmúpòwe.
10Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn,
wọ́n ń rí mi sá,
ara kò tì wọ́n láti tutọ́ sí mi lójú.
11Nítorí Ọlọrun ti sọ mí di aláìlera,
ó sì ti rẹ̀ mí sílẹ̀,
wọn dojú ìjà kọ mí ninu ibinu wọn.
12Àwọn oníjàgídíjàgan dìde sí mi ní apá ọ̀tún mi,
wọ́n lé mi kúrò,
wọ́n sì la ọ̀nà ìparun sílẹ̀ fún mi.
13Wọ́n dínà mọ́ mi,
wọ́n dá kún wahala mi,
kò sì sí ẹni tí ó lè dá wọn lẹ́kun.
14Wọ́n jálù mí, bí ìgbà tí ọpọlọpọ ọmọ ogun bá gba ihò ara odi ìlú wọlé,
wọ́n ya lù mí, wọ́n wó mi mọ́lẹ̀.
15Ìbẹ̀rù-bojo dé bá mi,
wọ́n ń lépa ọlá mi bí afẹ́fẹ́,
ọlà mi sì parẹ́ bí ìkùukùu.
16“Nisinsinyii, ẹ̀mí mi fò lọ ninu mi,
ọjọ́ ìjìyà sì dé bá mi.
17Ní òru, egungun ń ro mí,
ìrora mi kò sì dínkù.
18Ọlọrun fi ipá gba aṣọ mi,
ó fún mi lọ́rùn bí ọrùn ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ mi.
19Ó sọ mí sinu ẹrẹ̀,
mo dàbí eruku ati eérú.
20“Mo ké pè ọ́, Ọlọrun, O kò dáhùn,
mo dìde dúró, mo gbadura, o kò kà mí sí.
21O dojú ibinu kọ mí,
o fi agbára rẹ bá mi jà.
22O sọ mí sókè ninu afẹ́fẹ́,
ò ń bì mí síhìn-ín sọ́hùn-ún
láàrin ariwo ìjì líle.
23Dájúdájú mo mọ̀ pé o óo gbé mi lọ sí ipò òkú,
ilé tí o yàn fún gbogbo eniyan.
24Bí ẹni tí a ti là mọ́lẹ̀, tí kò lè dìde, bá ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ninu ìnira,
dájúdájú o kò tún ní gbé ìjà kò ó?
25Ṣebí mo ti sọkún nítorí àwọn tí wọ́n wà ninu ìṣòro rí,
tí mo sì káàánú àwọn aláìní.
26Ṣugbọn nígbà tí mo bá ń retí ohun rere,
ibi ní ń bá mi.
Nígbà tí mo bá sì ń retí ìmọ́lẹ̀,
òkùnkùn ni mò ń rí.
27Ọkàn mi dàrú, ara mi kò balẹ̀,
ọjọ́ ìpọ́njú dé bá mi.
28Mo fa ojú ro, mò ń káàkiri,
mo dìde nàró láti bèèrè ìrànlọ́wọ́ láàrin àwùjọ.
29Mò ń kígbe arò bí ajáko,
mo di ẹgbẹ́ ẹyẹ ògòǹgò.
30Àwọ̀ ara mi di dúdú, ó ń bó,
egungun mi gbóná fún ooru.
31Ọ̀fọ̀ dípò orin ayọ̀ fún mi,
ẹkún sì dípò ohùn fèrè.
Currently Selected:
:
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010