YouVersion Logo
Search Icon

LUKU 3:4-6

LUKU 3:4-6 YCE

Èyí rí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu ìwé ọ̀rọ̀ wolii Aisaya pé, “Ohùn ẹni tí ń kígbe ní aṣálẹ̀ pé, ‘Ẹ la ọ̀nà fún Oluwa, ẹ ṣe ojú ọ̀nà tí ó tọ́ fún un láti rìn! Gbogbo ọ̀gbun ni yóo jẹ́ dídí gbogbo òkè gíga ati òkè kéékèèké ni yóo jẹ́ rírẹ̀ sílẹ̀. A óo tọ́ ibi tí ó bá ṣe kọ́rọ-kọ̀rọ, a óo sì sọ ọ̀nà tí kò bá dán tẹ́lẹ̀ di dídán Gbogbo eniyan ni yóo rí ìgbàlà Ọlọrun.’ ”