LUKU 3
3
Iwaasu Johanu Onítẹ̀bọmi
(Mat 3:1-12; Mak 1:1-8; Joh 1:19-28)
1Ní ọdún kẹẹdogun tí Ọba Tiberiu ti wà lórí oyè, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ gomina Judia, tí Hẹrọdu jẹ́ baálẹ̀ Galili, tí Filipi arakunrin rẹ̀ jẹ́ baálẹ̀ Ituria ati ti agbègbè Tirakoniti, Lusaniu jẹ́ baálẹ̀ Abilene; 2Anasi ati Kayafa sì jẹ́ olórí alufaa. Johanu ọmọ Sakaraya gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní aṣálẹ̀ tí ó wà. 3Ó bá ń kiri gbogbo ìgbèríko odò Jọdani, ó ń waasu pé kí àwọn eniyan ronupiwada, kí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí Ọlọrun lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n. 4Èyí rí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu ìwé ọ̀rọ̀ wolii Aisaya pé,
“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní aṣálẹ̀ pé,
‘Ẹ la ọ̀nà fún Oluwa,
ẹ ṣe ojú ọ̀nà tí ó tọ́ fún un láti rìn!
5Gbogbo ọ̀gbun ni yóo jẹ́ dídí
gbogbo òkè gíga ati òkè kéékèèké
ni yóo jẹ́ rírẹ̀ sílẹ̀.
A óo tọ́ ibi tí ó bá ṣe kọ́rọ-kọ̀rọ,
a óo sì sọ ọ̀nà tí kò bá dán tẹ́lẹ̀ di dídán
6Gbogbo eniyan ni yóo rí ìgbàlà Ọlọrun.’ ”#Ais 40:3-5
7Johanu ń sọ fún àwọn eniyan tí ó jáde lọ ṣe ìrìbọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fun yín láti sá fún ibinu tí ń bọ̀?#Mat 12:34; 23:33 8Ẹ fihàn ninu ìwà yín pé ẹ ti ronupiwada. Ẹ má bẹ̀rẹ̀ láti máa rò ninu ara yín pé, ‘A ní Abrahamu ní baba.’ Nítorí mò ń sọ fun yín pé Ọlọrun lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu láti inú òkúta wọnyi.#Joh 8:33 9A sì ti fi àáké lé gbòǹgbò igi báyìí. Nítorí náà, igikígi tí kò bá máa so èso rere ni a óo gé lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná.”#Mat 7:19
10Àwọn eniyan wá bi í pé, “Kí ni kí a wá ṣe?”
11Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó bá ní dàńṣíkí meji, kí ó fún ẹni tí kò ní lọ́kan. Ẹni tí ó bá ní oúnjẹ níláti ṣe bákan náà.”
12Àwọn agbowó-odè náà wá láti ṣe ìrìbọmi. Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, kí ni kí a ṣe?”#Luk 7:29
13Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe gbà ju iye tí ó tọ́ lọ.”
14Àwọn ọmọ-ogun náà ń bi í pé, “Àwa náà ńkọ́, kí ni kí a ṣe?”
Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dẹ́rù ba ẹnikẹ́ni láti lọ́ wọn lọ́wọ́ gbà, Ẹ má ṣe fi ẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni. Ẹ jẹ́ kí owó oṣù yín to yín.”
15Àwọn eniyan ń retí, gbogbo wọn ń rò ninu ọkàn wọn bí Johanu bá ni Mesaya. 16Johanu sọ fún gbogbo eniyan pé, “Omi ni èmi fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́ fun yín, ṣugbọn ẹni tí ó jù mí lọ ń bọ̀. Èmi kò tó ẹni tíí tú okùn bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni yóo fi wẹ̀ yín mọ́. 17Àtẹ ìfẹ́kà ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ tí yóo fi fẹ́ ọkà inú oko rẹ̀; yóo kó ọkà rẹ̀ sinu abà, yóo sì sun fùlùfúlù ninu iná àjóòkú.”
18Ní ọ̀nà yìí ati ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà mìíràn, Johanu ń gba àwọn eniyan níyànjú, ó sì ń sọ̀rọ̀ ìyìn rere fún wọn. 19Ní àkókò kan, Johanu bá Hẹrọdu baálẹ̀ wí nítorí ọ̀ràn Hẹrọdiasi, iyawo Filipi, arakunrin rẹ̀, tí Hẹrọdu gbà. Ó tún bá a wí fún gbogbo nǹkan burúkú mìíràn tí ó ṣe. 20Hẹrọdu wá tún fi ti Johanu tí ó sọ sẹ́wọ̀n kún gbogbo ìwà burúkú rẹ̀.#Mat 14:3-4; Mak 6:17-18
Johanu Ṣe Ìrìbọmi fún Jesu
(Mat 3:13-17; Mak 1:9-11)
21Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan ń ṣe ìrìbọmi, Jesu náà ṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, bí ó ti ń gbadura, ọ̀run ṣí sílẹ̀. 22Ẹ̀mí Mímọ́ fò wálẹ̀ bí àdàbà ó bà lé e lórí. Ohùn kan wá fọ̀ láti ọ̀run pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi; inú mi dùn sí ọ gidigidi.”#Jẹn 22:2; O. Daf 2:7; Ais 42:1; Mat 3:17; Mak 1:11; Luk 9:35
Ìrandíran Jesu
(Mat 1:1-17)
23Jesu tó ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀. Ọmọ Josẹfu ni àwọn eniyan mọ̀ ọ́n sí. Josẹfu jẹ́ ọmọ Eli, 24ọmọ Matati, ọmọ Lefi, ọmọ Meliki, ọmọ Janai, ọmọ Josẹfu, 25ọmọ Matatiya, ọmọ Amosi, ọmọ Nahumu, ọmọ Esili, ọmọ Nagai, 26ọmọ Maati, ọmọ Matatiya, ọmọ Semehin, ọmọ Joseki, ọmọ Joda, 27ọmọ Johana, ọmọ Resa, ọmọ Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ọmọ Neri, 28ọmọ Meliki, ọmọ Adi, ọmọ Kosamu, ọmọ Elimadamu, ọmọ Eri, 29ọmọ Joṣua ọmọ Elieseri, ọmọ Jorimu, ọmọ Matati, ọmọ Lefi, 30ọmọ Simeoni, ọmọ Juda, ọmọ Josẹfu, ọmọ Jonamu, ọmọ Eliakimu, 31ọmọ Melea, ọmọ Mena, ọmọ Matati, ọmọ Natani, ọmọ Dafidi, 32ọmọ Jese, ọmọ Obedi, ọmọ Boasi, ọmọ Salimoni, ọmọ Naṣoni, 33ọmọ Aminadabu, ọmọ Adimini, ọmọ Arini, ọmọ Hesironi, ọmọ Pẹrẹsi, ọmọ Juda, 34ọmọ Jakọbu, ọmọ Isaaki, ọmọ Abrahamu, ọmọ Tẹra, ọmọ Nahori, 35ọmọ Serugi, ọmọ Reu, ọmọ Pelegi, ọmọ Eberi, ọmọ Sela, 36ọmọ Kainani, ọmọ Afasadi, ọmọ Ṣemu, ọmọ Noa, ọmọ Lamẹki, 37ọmọ Metusela, ọmọ Enọku, ọmọ Jaredi, ọmọ Mahalaleli, ọmọ Kenani, 38ọmọ Enọṣi, ọmọ Seti, ọmọ Adamu, ọmọ Ọlọrun.
Currently Selected:
LUKU 3: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: