YouVersion Logo
Search Icon

MATIU 25

25
Òwe nípa Àwọn Wundia Mẹ́wàá
1“Ní àkókò náà, ọ̀rọ̀ ìjọba ọ̀run yóo dàbí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn wundia mẹ́wàá, tí wọn gbé àtùpà wọn láti jáde lọ pàdé ọkọ iyawo.#Luk 12:35 2Marun-un ninu wọn jẹ́ òmùgọ̀, marun-un sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n. 3Àwọn òmùgọ̀ gbé àtùpà, ṣugbọn wọn kò gbé epo lọ́wọ́. 4Àwọn ọlọ́gbọ́n rọ epo sinu ìgò, wọ́n gbé e lọ́wọ́ pẹlu àtùpà wọn. 5Nígbà tí ọkọ iyawo pẹ́ kí ó tó dé, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí tòògbé, wọ́n bá sùn lọ.
6“Nígbà tí ó di ààrin ọ̀gànjọ́, igbe ta pé, ‘Ọkọ iyawo dé! Ẹ jáde lọ pàdé rẹ̀.’ 7Nígbà náà ni gbogbo àwọn wundia náà tají, wọ́n tún iná àtùpà wọn ṣe. 8Àwọn wundia òmùgọ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ àwọn ọlọ́gbọ́n pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún wa ninu epo yín, nítorí àtùpà wa ń kú lọ.’ 9Àwọn ọlọ́gbọ́n dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Epo tí a ní kò tó fún àwa ati ẹ̀yin. Ẹ kúkú lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ń ta epo, kí ẹ ra tiyín.’ 10Nígbà tí wọ́n lọ ra epo, ọkọ iyawo dé, àwọn tí wọ́n ti múra sílẹ̀ bá wọ ilé ibi igbeyawo pẹlu rẹ̀, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn.
11“Ní ìgbẹ̀yìn àwọn wundia yòókù dé, wọ́n ní, ‘Alàgbà, alàgbà, ẹ ṣílẹ̀kùn fún wa!’ 12Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé èmi kò mọ̀ yín.’#Luk 13:25
13“Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tabi àkókò.
Òwe nípa Àwọn Ẹrú Mẹta
(Luk 19:11-27)
14“Nígbà náà ìjọba ọ̀run yóo tún rí báyìí. Ọkunrin kan ń lọ sí ìdálẹ̀. Ó bá pe àwọn ẹrú rẹ̀, ó fi àwọn dúkìá rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́. 15Ó fún ọ̀kan ni àpò owó marun-un, ó fún ekeji ní àpò meji, ó fún ẹkẹta ní àpò kan. Ó fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bí agbára rẹ̀ ti tó; ó bá lọ sí ìdálẹ̀. 16Kíá, bí ó ti lọ tán, ẹni tí ó gba àpò marun-un lọ ṣòwò, ó bá jèrè àpò marun-un. 17Bákan náà ni ẹni tí ó gba àpò meji. Òun náà jèrè àpò meji. 18Ṣugbọn ẹni tí ó gba àpò kan lọ wa ilẹ̀, ó bá bo owó oluwa rẹ̀ mọ́lẹ̀.
19“Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, oluwa àwọn ẹrú náà dé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bi wọ́n bí wọ́n ti ṣe sí. 20Nígbà tí ẹni tí ó gba àpò marun-un dé, ó gbé àpò marun-un mìíràn wá, ó ní, ‘Alàgbà, àpò marun-un ni o fún mi. Mo ti jèrè àpò marun-un lórí rẹ̀.’ 21Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ olóòótọ́ ẹrú, eniyan rere ni ọ́. O ti ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré, a óo fi ọ́ ṣe alámòójútó nǹkan pupọ. Bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.’
22“Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tí ó gba àpò meji wá, ó ní ‘Alàgbà, àpò meji ni o fún mi. Mo ti jèrè àpò meji lórí rẹ̀!’ 23Oluwa rẹ̀ sọ fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ olóòótọ́ ẹrú, eniyan rere ni ọ́. O ti ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré, n óo fi ọ́ ṣe alámòójútó nǹkan pupọ. Bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.’
24“Lẹ́yìn náà, ẹni tí ó gba àpò kan wá, ó ní, ‘Alàgbà mo mọ̀ pé eniyan líle ni ọ́. Ibi tí o kò fúnrúgbìn sí ni o tí ń kórè. Ibi tí o kò fi nǹkan pamọ́ sí ni ò ń fojú wá a sí. 25Ẹ̀rù rẹ bà mí, mo bá lọ fi àpò kan rẹ pamọ́ sinu ilẹ̀. Òun nìyí, gba nǹkan rẹ!’
26“Olúwa rẹ̀ dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ olubi ati onímẹ̀ẹ́lẹ́ ẹrú yìí. O mọ̀ pé èmi a máa kórè níbi tí n kò fúnrúgbìn sí, ati pé èmi a máa fojú wá nǹkan níbi tí n kò fi pamọ́ sí. 27Nígbà tí o mọ̀ bẹ́ẹ̀, kí ni kò jẹ́ kí o fi owó mi fún àwọn agbowó-pamọ́ pé nígbà tí mo bá dé, kí n lè gba owó mi pada pẹlu èlé? 28Nítorí náà, ẹ gba àpò kan náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ fún ẹni tí ó ní àpò mẹ́wàá. 29Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a óo túbọ̀ fún, kí ó lè ní sí i. Lọ́wọ́ ẹni tí kò ní ni a óo sì ti gba ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ní.#Mat 13:12; Mak 4:25; Luk 8:18 30Kí ẹ mú ẹrú tí kò wúlò yìí kí ẹ tì í sinu òkùnkùn biribiri. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.’#Mat 8:12; 22:13; Luk 13:28 #Luk 19:11-27
Ìdájọ́ Àwọn Orílẹ̀-èdè
31“Nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá yọ ninu ìgúnwà rẹ̀ pẹlu gbogbo àwọn angẹli, nígbà náà ni yóo jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀.#a Mat 16:27; b Mat 19:28 32Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo péjọ níwájú rẹ̀, yóo wá yà wọ́n sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, bí olùṣọ́-aguntan tíí ya àwọn aguntan sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́. 33Yóo fi àwọn olódodo sí ọwọ́ ọ̀tún, yóo fi àwọn ìyókù sí ọwọ́ òsì. 34Nígbà náà ni ọba yóo sọ fún àwọn ti ọwọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bukun. Ẹ wá jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fun yín kí á tó dá ayé. 35Nítorí nígbà tí ebi ń pa mí, ẹ fún mi ní oúnjẹ. Nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ mí, ẹ fún mi ní omi mu. Nígbà tí mo jẹ́ àlejò, ẹ gbà mí sílé. 36Nígbà tí mo wà níhòòhò, ẹ daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣàìsàn, ẹ wá wò mí. Nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ wá sọ́dọ̀ mi.’#Sir 7:32-36
37“Nígbà náà ni àwọn olódodo yóo dáhùn pé, ‘Oluwa, nígbà wo ni a rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a fún ọ ní oúnjẹ, tabi tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́ tí a fún ọ ní omi mu? 38Nígbà wo ni a rí ọ níhòòhò tí a daṣọ bò ọ́? 39Nígbà wo ni a rí ọ tí o ṣàìsàn, tabi tí o wà lẹ́wọ̀n, tí a wá sọ́dọ̀ rẹ?’ 40Ọba yóo wá dá wọn lóhùn pé, ‘Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti ṣe é fún ọ̀kan ninu àwọn arakunrin mi tí ó kéré jùlọ, èmi ni ẹ ṣe é fún.’
41“Nígbà náà ni yóo wá sọ fún àwọn tí ó wà ní ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún. Ẹ lọ sinu iná àjóòkú tí a ti pèsè sílẹ̀ fún èṣù ati àwọn angẹli rẹ̀. 42Nítorí nígbà tí ebi ń pa mí, ẹ kò fún mi ní oúnjẹ jẹ. Òùngbẹ ń gbẹ mí, ẹ kò fún mi ní omi mu. 43Mo jẹ́ àlejò, ẹ kò gbà mí sílé. Mo wà ní ìhòòhò, ẹ kò daṣọ bò mí. Mo ṣàìsàn, mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ kò wá wò mí.’
44“Nígbà náà ni àwọn náà yóo bi í pé, ‘Oluwa, nígbà wo ni a rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tabi tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́, tabi tí o jẹ́ àlejò, tabi tí o wà ní ìhòòhò, tabi tí o ṣàìsàn, tabi tí o wà lẹ́wọ̀n, tí a kò bojútó ọ?’ 45Yóo wá dá wọn lóhùn pé, ‘Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò ti ṣe é fún ọ̀kan ninu àwọn tí ó kéré jùlọ wọnyi, èmi ni ẹ kò ṣe é fún.’ 46Àwọn wọnyi ni yóo lọ sinu ìyà àìlópin. Ṣugbọn àwọn olódodo yóo wọ ìyè ainipẹkun.”#Dan 12:2

Currently Selected:

MATIU 25: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in