YouVersion Logo
Search Icon

MATIU 6

6
Ẹ̀kọ́ nípa Ìtọrẹ Àánú
1“Ẹ ṣọ́ra nígbà tí ẹ bá ń ṣe iṣẹ́ ẹ̀sìn yín, ẹ má máa hùwà ṣe-á-rí-mi, kí àwọn eniyan baà lè rí ohun tí ẹ̀ ń ṣe. Bí ẹ bá ń hùwà ṣe-á-rí-mi, ẹ kò ní èrè lọ́dọ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.#Mat 23:5
2“Nítorí náà, nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má ṣe gbé agogo síta gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣehàn tí ń ṣe ninu àwọn ilé ìpàdé ati ní ojú títì ní ìgboro, kí wọn lè gba ìyìn eniyan. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 3Ṣugbọn nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má tilẹ̀ jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe; 4kí ìtọrẹ àánú rẹ jẹ́ ohun ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ yóo sì san ẹ̀san rẹ fún ọ.#6:4, 6:6 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn fi gbolohun kan kún èyí pé, ní gbangba.
Ẹ̀kọ́ nípa Adura
(Luk 11:2-4)
5“Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má ṣe bí àwọn aláṣehàn. Nítorí wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa dúró gbadura ninu ilé ìpàdé ati ní ẹ̀bá títì, kí àwọn eniyan lè rí wọn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.#Luk 18:10-14 6Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbadura, wọ inú yàrá rẹ lọ, ti ìlẹ̀kùn rẹ, kí o gbadura sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san rẹ fún ọ.
7“Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má máa wí nǹkankan náà títí, bí àwọn abọ̀rìṣà ti ń ṣe. Nítorí wọ́n rò pé nípa ọ̀rọ̀ pupọ ni adura wọn yóo ṣe gbà.#Sir 7:14 8Ẹ má ṣe fara wé wọn, nítorí Baba yín ti mọ ohun tí ẹ nílò kí ẹ tó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. 9Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ̀yin máa gbadura:#Jak 5:2-3
‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run:
Kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ rẹ,
10kí ìjọba rẹ dé,
ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayé
bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run.
11Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí.
12Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá
gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti dárí ji àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ wá.
13Má fà wá sinu ìdánwò,
ṣugbọn gbà wá lọ́wọ́ èṣù.’#6:13 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn ní àfikún báyìí: nítorí ìjọba ni tìrẹ, ati agbára ati ògo títí lae. Amin.
14“Nítorí bí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan jì wọ́n, Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóo dáríjì yín.#Sir 28:1-5 15Ṣugbọn bí ẹ kò bá dáríjì àwọn eniyan, Baba yín kò ní dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.#Mak 11:25-26
Ẹ̀kọ́ nípa Ààwẹ̀ Gbígbà
16“Nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ má máa ṣe bí àwọn aláṣehàn tí wọ́n máa ń fajúro, kí àwọn eniyan lè rí i lójú wọn pé wọ́n ń gbààwẹ̀. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 17Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbààwẹ̀, bọ́jú kí o sì fi nǹkan pa ara,#Jud 10:3 18kí ó má baà hàn sí àwọn eniyan pé ò ń gbààwẹ̀, àfi sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san fún ọ.#6:18 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn ní àfikún báyìí: ní gbangba.
Ìṣúra ní Ọ̀run
(Luk 12:33-34)
19“Ẹ má ṣe kó ìṣúra jọ fún ara yín ní ayé, níbi tí kòkòrò lè bà á jẹ́, tí ó sì lè dógùn-ún. Àwọn olè tún lè wá a kàn kí wọ́n jí i lọ. 20Ṣugbọn ẹ kó ìṣúra jọ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí kòkòrò kò lè bà á jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò lè dógùn-ún, àwọn olè kò sì lè wá a kàn kí wọ́n jí i lọ níbẹ̀.#Sir 29:11 21Nítorí níbi tí ìṣúra rẹ bá wà, níbẹ̀ náà ni ọkàn rẹ yóo wà.
Ìmọ́lẹ̀ Ara
(Luk 11:34-36)
22“Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Bí ojú rẹ bá ríran kedere, gbogbo ara rẹ yóo ní ìmọ́lẹ̀. 23Ṣugbọn bí ojú rẹ kò bá ríran tààrà, gbogbo ara rẹ ni yóo ṣókùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ tí ó wà ninu rẹ bá wá di òkùnkùn, báwo ni òkùnkùn náà yóo ti pọ̀ tó!
Ọlọrun ati Ohun Ìní Eniyan
(Luk 16:13; 12:22-31)
24“Kò sí ẹni tí ó lè sin oluwa meji. Nítorí ọ̀kan ni yóo ṣe: ninu kí ó kórìíra ọ̀kan, kí ó fẹ́ràn ekeji, tabi kí ó fara mọ́ ọ̀kan, kí ó má ka ekeji sí. Ẹ kò lè sin Ọlọrun, kí ẹ tún máa bọ owó.
25“Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kí ẹ má máa ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, pé kí ni ẹ óo jẹ tabi kí ni ẹ óo mu,#6:25 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn fi gbolohun yìí kún un pé: tabi kí ni ẹ óo mu. tabi pé kí ni ẹ óo fi bora. Mo ṣebí ẹ̀mí yín ju oúnjẹ lọ; ati pé ara yín ju aṣọ lọ. 26Ẹ wo àwọn ẹyẹ lójú ọ̀run. Wọn kì í fúnrúgbìn, wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kó nǹkan oko jọ sinu abà. Sibẹ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Mo ṣebí ẹ̀yin sàn ju àwọn ẹyẹ lọ! 27Ta ni ninu yín tí ó lè ṣe àníyàn títí tí ó lè fi kún ọjọ́ ayé rẹ̀?
28“Kí ní ṣe tí ẹ̀ ń ṣe àníyàn nípa ohun tí ẹ óo wọ̀? Ẹ ṣe akiyesi àwọn òdòdó inú igbó bí wọ́n ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. 29Sibẹ mo sọ fun yín pé Solomoni pàápàá ninu gbogbo ìgúnwà rẹ̀ kò lè wọ aṣọ tí ó lẹ́wà bíi ti ọ̀kan ninu àwọn òdòdó yìí.#1 A. Ọba 10:4-7; 2Kron 9:3-6 30Ǹjẹ́ bí Ọlọrun bá wọ koríko ìgbẹ́ láṣọ báyìí, koríko tí yóo wà lónìí, tí a óo fi dáná lọ́la, mélòó-mélòó ni yóo wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré?
31“Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn pé kí ni ẹ óo jẹ? Tabi, kí ni ẹ óo mu? Tabi kí ni ẹ óo fi bora? 32Nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni àwọn abọ̀rìṣà ń lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo wọn. 33Ṣugbọn ẹ kọ́kọ́ máa wá ìjọba Ọlọrun ná ati òdodo rẹ̀, gbogbo nǹkan wọnyi ni a óo fi kún un fún yín. 34Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn nípa nǹkan ti ọ̀la; nítorí ọ̀la ni nǹkan ti ọ̀la wà fún; wahala ti òní nìkan ti tó fún òní láì fi ti ọ̀la kún un.

Currently Selected:

MATIU 6: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in