YouVersion Logo
Search Icon

NEHEMAYA 1:7-9

NEHEMAYA 1:7-9 YCE

A ti hùwà burúkú sí ọ, a kò sì pa àwọn òfin, ati ìlànà ati àṣẹ rẹ tí o pa fún Mose iranṣẹ rẹ mọ́. Ranti ìlérí tí o ṣe fún Mose, iranṣẹ rẹ, pé, ‘Bí ẹ kò bá jẹ́ olóòótọ́, n óo fọn yín káàkiri sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, ṣugbọn tí ẹ bá pada sọ́dọ̀ mi, tí ẹ pa òfin mi mọ́, tí ẹ sì ń tẹ̀lé e, bí ẹ tilẹ̀ fọ́nká lọ sí ọ̀nà jíjìn réré, n óo ṣà yín jọ, n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti yàn pé ẹ óo ti máa sìn mí kí orúkọ mi lè máa wà níbẹ̀.’

Free Reading Plans and Devotionals related to NEHEMAYA 1:7-9